Ijọba ipinlẹ Eko ti kede konilegbele oni wakati mẹrinlelogun

Lati aago mẹrin ọjọ Isegun, Tusidee, ọsẹ yii, ijọba ipinle Eko ti kede konilegbele kaakiri ipinlẹ naa. Wọn ni ẹnikẹni ko gbọdọ si loju titi, yatọ si awọn ti iṣẹ wọn ba jẹ mọ bẹẹ lati wa nibe.

Gomina Sanwo-Olu ni, ‘‘O jẹ ohun to ya ni lẹnu pe iwọde wọọrọwọ ti awọn ọdọ n ṣe lati fi ẹhonu han lodi si SARS ti waa di ẹrujẹjẹ, to si ti fẹẹ ṣakoba fun igbaye-gbadun awọn araalu. Ẹmi ti sọnu, bẹẹ ni ọpọ padanu agọ ara wọn pẹlu bi awọn ọmọọta kan ṣe sa sabẹ iwọde yii lati maa da wahala silẹ.

‘‘Gẹgẹ bii ijọba to mọ ojuṣe rẹ si araalu, a ko ni i maa woran ki idarudapọ maa ṣẹlẹ ninu ilu bo tilẹ jẹ pe awa naa fara mọ ifẹhonu han awọn ọdọ lori ọrọ SARS

‘’Nidii eyi, mo pasẹ konilegbele oni wakati mẹrinlelogun kaakiri ipinlẹ Eko, bẹrẹ lati aago mẹrin irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu kẹwaa yii. A ko fẹẹ ri ẹnikẹni loju popo yatọ si awọn ti wọn n ṣiṣẹ ilu to jẹ mọ ki wọn wa nibẹ laarin asiko naa.’’ Gomina ipinle Eko lo kede beẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

One comment

  1. Ohun ti ijoba so ti da

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: