Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Yinka Odumakin bẹrẹ irinajo sile ikẹyin, ijọba ipinlẹ Ọṣun gba oku rẹ lọwọ ijọba Eko ni Aṣejirẹ.
Aago meji kọja iṣẹju mẹwaa ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ni Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Dokita Charles Akinọla, ẹni to ko awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun bii mẹwaa sodi lọ sibẹ lati gba oku akọni naa, ti wọn si fori le ilu Moro.
Abẹ biriiji orita ilu Gbọngan ni agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan nipinlẹ Ọṣun, Coalition of Osun Civil Societies, ti duro lati gba oku rẹ, lẹyin ti wọn si kọrin fun un tan ni gbogbo wọn kọja siluu Moro, niluu abinibi Yinka.