Ijọba ipinlẹ Ogun fẹẹ ba ọlọpaa mẹrin ṣẹjọ lori ẹsun ipaniyan lasiko iwọde SARS

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti sọ pe ijọba oun yoo ba awọn ọlọpaa mẹrin kan ṣe ẹjọ lori ẹsun ipaniyan, eyi to kan wọn lori iku awọn araalu kan lasiko iwọde ifopin si SARS to waye lọsẹ to kọja.

Ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa yii, ni Abiọdun sọ eyi di mimọ, bẹẹ lo fi orukọ awọn ọlọpaa naa lede. Ẹni akọkọ ninu wọn ti ẹjọ ipaniyan rẹ yoo kọkọ waye ni Inspẹkitọ Wasiu Lawal. Ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ni igbẹjọ ẹsun ipaniyan rẹ yoo waye ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun, ẹka ti Ipokia.

Ọlọpaa keji ti yoo jẹjọ iṣeeṣi-paniyan ni Okoi Obi. Ọjọ keji, oṣu kẹjila, ọdun 2020 yii, ni igbẹjọ tiẹ yoo waye. Ẹka ile-ẹjọ giga Ijẹbu-Ode ni wọn yoo si ti gbọ ẹjọ tiẹ.

Inspẹkitọ Niyi Ogunsoro ni ọlọpaa kẹta ti ijọba loun yoo ba ṣẹjọ ipaniyan. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i gbe ọjọ ti yoo foju kan kootu jade ni tiẹ, kootu giga niluu Abẹokuta ni wọn sọ pe oun yoo ti jẹjọ.

Ẹni kẹrin ninu awọn ọlọpaa naa ni wọn pe orukọ ẹ ni Inspẹkitọ Ahmed Mohammed. Ẹsun ipaniyan ni wọn fi  kan oun naa. Ẹka ile-ẹjọ giga to wa n’Ilaro ni gomina sọ pe ẹjọ tiẹ yoo ti waye, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede ọjọ ti yoo foju ba kootu lasiko ti a pari iroyin yii.

Ijọba ipinlẹ Ogun waa rọ awọn araalu lati maa fọkan ba awọn ẹjọ yii bọ, ki wọn si ma ṣe gbagbe lati da si i bi wọn ba ni ẹri to nipọn.

Atẹjade ti gomina fi sọ ọrọ yii di mimọ tẹsiwaju pe kawọn araalu fi iwe ifisun lori iya aitọ to ba jẹ wọn lasiko iwọde naa ṣọwọ si igbimọ to n ri si ẹsun bii eyi ti ijọba ti gbe kalẹ nipinlẹ Ogun, ti wọn si ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu.

Beeyan ba waa fẹẹ ba awọn olugbeja yii sọrọ lori foonu, eyi ni awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ tijọba fi sita :07080601223, 07080601224  ati 07080601225.

 

Leave a Reply