Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa apapọ orileede yii ti paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo awọn agbofinro ati ẹṣọ alaabo ti wọn n ṣọ gomina ipinlẹ Kogi ana, Alaaji Yahaya Bello, kuro lẹyẹ-o-sọka, amọ ki i ṣe pe wọn ja Bello sokolombo nikan, niṣe ni wọn tun rọ awọn ọlọpaa naa da sahaamọ, latari iwadii ijinlẹ to n lọ lọwọ lori awọn ẹsun iwa ibajẹ, jibiti lilu ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ti wọn fi kan gomina tẹlẹri ọhun.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin yii, ni aṣẹ wa latoke, lati ọdọ ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, ninu lẹta kan to fi ṣọwọ sileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, o ni, “Ileeṣẹ ọlọpaa ti paṣẹ pe ki ẹ ko gbogbo awọn olọpaa, awọn ẹṣọ alaabo, ati ọlọpaa gbogbo to wa lẹyin gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Alaaji Yahaya Bello, kuro lẹsẹkẹsẹ tẹ ẹ ba ti gba lẹta yii. Ẹ jẹ ki n mọ ti aṣẹ yii ba ti tẹ yin lọwọ, kẹ ẹ si jẹ ki n mọ tẹ ẹ ba ti ṣe bi mo ṣe wi.”
Latari aṣẹ yii, loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti wọn n wọ tẹle Yahaya Bello ti palẹ ẹru wọn mọ, ti wọn si ti kọri si olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, gẹgẹ bi wọn ṣe pa wọn laṣẹ.
Bakan naa, ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ si i fi pampẹ ofin gbe awọn kan lara awọn ẹṣọ alaabo ọhun, lati mọ bi wọn ṣe jẹ ki Yahaya Bello raaye sa lọ mọ awọn ẹṣọ EFCC lọwọ, nigba ti wọn fẹẹ fi pampẹ ọba mu un lọjọ diẹ sẹyin.
A gbọ pe ẹka ileeṣẹ ti wọn tọpinpin iwa ọdaran to wa lolu-ileeṣẹ ọlọpaa apapọ, Criminal Investigation Department, Federal Capital Territory, niluu Abuja, ni wọn ko ọlọpaa abọbaku kan to jẹ obinrin, to wa lara awọn ẹṣọ alaabo Bello, atawọn ọlọpaa mi-in lọ, ibẹ ni wọn ti n fi ibeere po wọn nifun pọ lọwọlọwọ.
Lafikun si eyi, ninu atẹjade mi-in ti ileeṣẹ to n ri si ijade ati iwọle nilẹ wa, iyẹn Nigeria Immigration Service, fi ṣọwọ si ileeṣẹ aṣọbode, Nigeria Custom Service, ti wọn si tun fi ẹda rẹ sọwọ si ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ijọba to n ri si awọn ọrọ abẹle, ati ẹka ileeṣẹ ijọba to n ṣakoso ẹrọ ayelujara, Nigeria Internet Services, wọn ta gbogbo awọn ileeṣẹ yii lolobo pe ki wọn wa lojufo, ki wọn si ta mọra lori ọrọ Yahaya Bello, tori ijọba n wa a loju mejeeji, wọn o si gbọdọ jẹ ko raaye yọ pọrọ jade kuro lorileede yii.
Atẹjade naa ni, ẹnikẹni to ba ri Yahaya Bello nibi to ti fẹẹ jade niluu, ẹ tete dari ẹ si Darẹkitọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ, tabi kẹ ẹ pe nọmba foonu 08036226329 loju-ẹsẹ.
Ẹ oo ranti pe lọjọ meji sẹyin ni ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati jibiti nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), kede pe awọn n wa Yahaya Bello fun ẹsun kikowo ilu pamọ soke okun, wọn ni ọgọrin biliọnu Naira, miliọnu lọna ojilerugba o le mẹfa, ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo ati mẹwaa, ojidinlaaadọrun-un Naira (N80,246,470,088.88) lo gbọdọ kawọ pọnyin rojọ bo ṣe poora mọ ọn lọwọ lasiko iṣakoso rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kogi.