Wọn ti ri i mu o, dẹrẹba to pa tọkọ-tiyawo sinu ile wọn l’Abuja

Monisọla Saka

Amookunṣika ẹda to pa awọn arugbo tọkọ-taya kan niluu Abuja, ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, Jonathan Marcus, ti n ṣẹju pako lakolo awọn ọlọpaa.

Ọkunrin afurasi to n ṣiṣẹ atọkọṣe (Mechanic) yii, ni ọwọ awọn agbofinro tẹ nitori iku oro to fi pa awọn baba ati iya agbalagba ti wọn n gbe lagbegbe Apo Legislative Quarters, niluu Abuja ọhun.

Awakọ awọn oloogbe nigba kan ri ni wọn pe Marcus.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni kọmiṣanna ọlọpaa ilu Abuja, Benneth Igweh, foju afurasi atawọn mi-in hande.

Igweh ni ni kete ti wọn waa fẹjọ ẹni to ṣeku pa Ọgbẹni Adebọla Ezekiel, ẹni ọgọrin ọdun (80) atiyawo ẹ, Abiọdun Ezekiel, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin (79), sinu ile wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn ti bẹrẹ iwadii, ti ọwọ awọn si pada tẹ afurasi.

Ilu Ọbajana, nipinlẹ Kogi, nibi ti afurasi fara soko si ni awọn ọlọpaa tọpasẹ rẹ lọ, ti wọn si ti mu un.

Igweh ni lasiko ti ọmọkunrin naa n ṣalaye ohun to mọ nipa iku awọn oloogbe ọhun,  lo sọ pe oun loun yọ wọle lọjọ naa, toun fi nnkan la awọn oloogbe mejeeji lọna ọfun. Lẹyin naa loun ko gbogbo foonu wọn ati kaadi ATM ti wọn fi maa n gbowo sa lọ.

Lẹyin ti iṣẹlẹ yii waye ni ọkan lara ọmọ awọn oloogbe n pe foonu awọn obi rẹ, ṣugbọn ti wọn ko gbe e.

Awọn aladuugbo ni ọkunrin naa pe pe ki wọn ba oun wo baba ati mama oun ninu ile.

Iyalẹnu lo jẹ fawọn tọhun nigba ti wọn ba ilẹkun ni titi pa, ti wọn ko si gbọ idahun ẹnikẹni to le ṣilẹkun fun wọn latinu ile.

Lẹyin tọmọ oloogbe fun wọn laṣẹ lati jalẹkun tabi windo wọle, ni wọn ba baba ati mama naa ninu agbara ẹjẹ, latari bi ọdaju ẹda naa ṣe ti fọbẹ ge wọn lọna ọfun.

Ọga ọlọpaa ni awọn yoo foju afurasi bale ẹjọ, ti iwadii ba ti pari.

Leave a Reply