Baba at’ọmọ ti wọn pa iya onipọnmọ l’Ogijo ti ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ

Monisọla Saka

Ṣe ẹ ranti iṣẹlẹ aburu kan tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe o waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, niluu Ogijo, nigba tọrọ teburu tobinrin kan fi n patẹ pọnmọ rẹ dija silẹ laarin, Micheal, alajọgbele rẹ, ati baba Micheal, Ọgbẹni Chijoke.

Ọjọ keji ija naa lobinrin ọhun, Abilekọ Tọpẹ Ọwọade, sọ pe inu n run oun, ti ẹjẹ sin jade loju ara rẹ, ka too wi ka too fọ, o daku, o si ṣe bẹẹ ku fin-in fin-in.

Amọ ko too ku, o fẹsun kan Micheal pe o gba oun nikuuku nikun lasiko tawọn n ja. Ariwo Micheal to pa yii lo mu ki ọkọ obinrin naa atawọn aladuugbo ke sawọn ọlopaa, ti wọn fi lọọ fi pampẹ ofin gbe Micheal ati baba rẹ ọhun.

Laipẹ yii, ALAROYE fọrọ wa awọn mejeeji lẹnu wo lakolo ọtẹlẹmuyẹ ti wọn wa, eyi lalaye ti baba atọmọ ṣe nipa bọrọ ọhun ṣe jẹ…

 

MICHEAL
Orukọ mi ni Micheal.

Mo n gbe ni Agbọwa, ni adugbo First Pipeline, lagbegbe Ogijo.

Ọmọọdun mẹtadinlogun ni mi.

Ọrọ obinrin kan to n gbe lẹyin ile landọọdu wa lo sọ mi dero teṣan ọlọpaa. Obinrin yẹn ni teburu kan, o maa n ta pọnmọ lori ẹ, teburu yẹn wa niwaju ita ile to n gbe, ile kan naa la si jọ n gbe.

Ọpọ igba lo maa n ba wa ja pe ka yee jokoo sori teburu yẹn, o ni to ba bajẹ, awa la maa tun un ṣe, tori ọpọ eeyan naa lo n jokoo sori ẹ.

Lọjọ keji, nigba ti mo de lati ibi ọja ti mo n ta, emi kan jokoo sori teburu yẹn ni, tori o ti rẹ mi, ọkunrin kan to n ṣiṣẹ sikiọriti naa jokoo, a jọọ jokoo sori teburu yẹn ni, a dẹ jọ n sọrọ, tori emi ṣi n reti ki baba de lati ibiiṣẹ wọn.

Emi o mọ pe obinrin yẹn n bọ lẹyin mi, nigba to n dari bọ lati ode to lọ. Bo ṣe de ẹyin mi, o kan fọ mi leti latẹyin ni, bo ṣe ri wa lori teburu, o tun bu aṣọ mi so lejika, o ni ṣebi oun ti sọ fun wa pe ka yee jokoo sori teburu oun.

Mo ni ṣebi o sọ pe a maa tun un ṣe to ba bajẹ ni. Ibẹ ṣaa la ti bẹrẹ si i ja, emi si n gbiyanju lati yẹra fun un, tori o mu apola igi kan dani, o loun maa la a mọ mi lori, mi o si fẹ ko la a mọ mi lori.

Nibi ta a ti n ja yẹn, o ṣubu, o tun dide. Ki n too mọ nnkan to n ṣẹlẹ, awọn alajọgbele ati aladuugbo ti pejọ le wa lori. Dadi mi naa ti de, ẹnu ija ni wọn ba wa.

Obinrin yii ṣaa tun lọọ gbe igi, o fẹẹ la a mọ mi, o dẹ ri dadi mi lori iduro o, o dẹ tun ṣẹẹkẹ eebu si wọn loriṣiiriṣii. Emi ṣaa di i lọwọ mu pe ko ma lọọ la igi ọwọ ẹ mọ mi, ibẹ ni igi yẹn ti lọọ ba dadi mi.

Nigba to ya, awọn eeyan la wa, wọn ba wa da si i, a dẹ pari ija yẹn lalẹ ọjọ yẹn.

Laaarọ ọjọ keji, ti mo ri i, mo ki i, mo tun bẹ ẹ pe ko ma binu ana o, o de loun ti gbọ. Emi dẹ lọ ṣẹnu iṣẹ mi ni temi. Nigba ti mo dari de lalẹ ni lanlọọdu wa pe mi, wọn ni obinrin temi atiẹ jọọ ja lalẹ ana, ẹjẹ ti n da lara ẹ. Ẹjẹ bawo kẹ, ẹnu ya mi. Mo lọọ wo obinrin naa, lo ba n sọ pe emi gba oun lẹṣẹẹ nikun nigba ta a n ja, emi o dẹ gba a lẹṣẹẹ nikun o, ibẹ lo ṣaa ti tun fẹẹ di mọ mi, o ni ẹjẹ n jade loju ara oun.

Awọn araale ni wọn n sọ fun wa pe lanlọọdu lo pe nọọsi kan to waa tọju ẹ, ti wọn si ra oogun fun un to lo. Gbogbo ẹ ti su mi lalẹ ọjọ yẹn, ilẹ dẹ ti ṣu, nnkan bii aago mẹwaa ti fẹẹ lu. Ki n too mọ nnkan to n ṣẹlẹ, wọn lobinrin yẹn ti daku o, lati ori didaku, wọn loo ti ku patapata, ọran de!

Nibẹ lawọn araadugbo ti lọọ pe ọlọpaa waa mu emi ati dadi mi, wọn lawa la pa a. Ibẹ ni wọn ti ko wa wa si teṣan ọlọpaa o.

Nigba tobinrin yẹn n ba mi kodimu, singilẹẹti to wa lọrun mi lemi fi n ja ọwọ ẹ kuro lara mi o, mi o lu u o. Koda lalẹ ọjọ ta a jọ ja, o ṣi lọ si iṣọ oru ni ṣọọṣi wọn o.

Ẹbi ti wọn n da mi ni pe mo gba a lẹṣẹẹ nikun, emi o dẹ gba a lẹṣẹẹ nikun.

Mo kẹkọọ arikọgbọn o, bi ẹnikẹni ba sọ pe ki n ma fọwọ kan nnkan awọn bayii, mi o jẹ tun sun mọ nnkan naa o. O dun mi pe obinrin yẹn ku.

Mo bẹ ijọba pe ki wọn fori jin mi o, tori emi gan-an bẹ obinrin yẹn ko too ku. Ti wọn ba le fi eyi fa mi leti, mi o jẹ rin ni bebe ija mọ laye mi o.

 

BABA MICHEAL
Chijoke Obiadada lorukọ mi. Ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (59) ni mi. Mo n gbe ni adugbo First Pipeline, iṣẹ aṣọ okirika tita ni mo n ṣe, mo n kiri ni.

Mi o le sọ ohun to ṣẹlẹ, tori lalẹ ọjọ Tọsidee to kọja lọhun-un ni o, o ti to nnkan bii aago mẹjọ alẹ nigba yẹn, emi ṣẹṣẹ de lati ibi itaja mi ni, mo ri i pe obinrin yii ati ọmọ mi, Micheal, wọn n ṣe fa-n-fa-a, mo ri i pe obinrin yii fa igi kan yọ, o fẹẹ la a mọ ọmọ mi, mo si ko saarin wọn lati la wọn, ibẹ lo ti la igi yẹn mọ mi lori, o la a mọ ọmọ naa lori, igi ọhun si da si meji.

Emi atawọn aladuugbo to wa nitosi ṣaa la wọn, a dẹ sẹtuu ija yẹn, ọrọ teburu obinrin naa lo dija silẹ, tori o ti maa n ṣekilọ pe kawọn eeyan yee jokoo sori teburu oun, amọ ọpọ awọn to wa laduugbo naa ni wọn saaba maa n jokoo sori ẹ.

Lalẹ ọjọ yẹn, obinrin yii lọ si Iṣọ Oru ni ṣọọṣi ẹ, iyẹn lẹyin ta a yanju ija yẹn o. Ni afẹmọju to n dari bọ lati iṣọ oru, o pade mi nita, nibi temi jokoo si, o dẹ bẹ mi pe ki n ma binu ana o, mo ni iyẹn ti lọ, a kira daadaa. Ko pẹ ni kaluku lọ sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ rẹ. Nigba ti mo dari de lalẹ, lanlọọdu pe mi pe obinrin toun atọmọ mi jọọ ja lanaa, inu ma n run un, mo ni inu rirun bii ti bawo, mo si lọọ wo o.

Ko jọ pe o loyun o, ko tiẹ loyun. Nigba ti mo lọọ wo o, mo dabaa pe ka gbe e lọ sọsibitu, lanlọọdu waa ni oun ti pe nọọsi kan lati waa tọju ẹ. Emi tiẹ n sọ pe ọrọ iru eleyii ki i ṣe eyi ta a maa maa pe nọọsi si, pe ka gbe e lọ sọsibitu ni, tori niṣe ni wọn ni ẹjẹ n ya lara ẹ. Emi ṣaa sọ temi.

Ko ju iṣẹju diẹ lẹyin naa ni wọn sọ fun mi pe obinrin yẹn ti ku. Lanlọọdu sọ fun mi pe kin ni mo fẹẹ waa ṣe bayii, mo ni kin ni mo fẹẹ ṣe, mi o le sa lọ, to ba jẹ emi ni mo pa a ni mo le maa sa kiri, mo ni ko sibi ti mo n lọ. Ibẹ ṣa lawọn ọlọpaa ti waa mu emi at’ọmọ mi.

O ba mi lẹru ṣa pe obinrin yẹn ku bẹẹ yẹn, o ya mi lẹnu gidi ni. Mi o ro pe ija ti wọn ja lalẹ ọjọ to ṣaaju lo ṣokunfa iku ẹ o, tori ko si nnkan kan to waye to le ṣokunfa iru iku ojiji bẹẹ.

Mo ti kẹkọọ arikọgbọn ninu iṣẹlẹ yii o, mo kẹkọọ pe o yẹ keeyan maa ko ara ẹ nijaanu, ti wahala ba n bọ, ibaa jẹ kekere, o yẹ keeyan sa, teeyan ba ṣe mi loni-in, ma a maa wo o ni o, dipo ki n gbara ta, ma a kuku fa a le Ọlọrun lọwọ. Tori eleyii ti kọ mi lọgbọn o.

Leave a Reply