Ijọba mi ko bẹru iwadii lori ikowojẹ – Fayẹmi

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmowe Kayọde Fayẹmi, ti sọ pe ijọba oun ko bẹru iwadii ti ẹnikẹni le fẹẹ ṣe lori ikowojẹ nitori gbogbo awọn igbesẹ lo ni akọsilẹ, eyi loun si fi gbe ofin to de iṣẹ akanṣe ijọba kalẹ kawọn eeyan le ri bi oun ṣe n nawo.

Fayẹmi ni gbogbo awọn iṣẹ akanṣẹ tijọba n ṣe ni alakalẹ wọn wa lori eka ayelujara ijọba, kawọn araalu le ṣegbeyẹwo ati iwadii awọn nnkan to n lọ, kijọba si le ṣi aṣọ loju gbogbo eto to n ṣe.

Gomina naa sọrọ yii latẹnu Kọmiṣanna feto isuna, Ọnarebu Fẹmi Ajayi, nibi idanilẹkọọ ọlọjọ mẹta tijọba ṣagbekalẹ lopin ọsẹ to kọja lori igbelarugẹ ṣiṣe otitọ lori awọn nnkan tijọba n nawo le lori, eyi ti ajọ Public Private Development Centre (PPDC) ṣagbekalẹ pẹlu iranlọwọ ajọ MacArthur Foundation.

Fayẹmi ni, ‘‘A mọ pe ki ijọba too le sọ pe awọn ṣiṣẹ takuntakun lati gbe eto ọrọ-aje larugẹ, awọn araalu gbọdọ lọwọ si i. Ka too ṣagbekalẹ eto isuna ọdun 2018, 2019, 2020 ati 2021, a ṣepade pẹlu araalu ni gbogbo ẹkun idibo mẹtẹẹta ta a ni nipinlẹ Ekiti, gbogbo isọri araalu ni wọn si ni aṣoju. Nibẹ lawọn eeyan ti beere nnkan ti wọn fẹ bii ileewe, ọsibitu, gbọngan ilu, ojupopo atawọn nnkan mi-in.

‘‘Awa ko bẹru iwadii lori ikowojẹ tabi ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu nitori ko si nnkan ta a n fi pamọ fawọn eeyan.

‘‘Gbogbo iṣẹ akanṣe ta a n ṣe lawọn eeyan yoo maa ri lori ikanni intanẹẹti wa.’’

Bakan naa ni Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Adebimpe, ti Ọgbẹni James Owolabi to jẹ ọga-agba ileeṣẹ eto ẹkọ ṣoju fun ati adari ajọ iṣẹ akanṣe ijọba (Ekiti State Bureau of Public Procurement) fidi ẹ mulẹ pe ijọba n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn eeyan ilu ti iṣẹ akanṣẹ ba ti n lọ lati ṣagbekalẹ ojulowo iṣẹ, bẹẹ lawọn eeyan ti lanfaani lati mọ idi ti iṣẹ akanṣẹ kan fi dawọ duro.

Ninu alaye tiẹ, ọga-agba PPDC, ẹka tipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Nelson Akerele, sọ ọ di mimọ pe ajọ ọhun ti ran ijọba lọwọ lati gbe ikanni kalẹ, nibi ti wọn yoo ti maa kede iṣẹ akanṣe to ba wa kawọn agbaṣẹṣe le fifẹ han, ki araalu si le mọ iye ti wọn n gba.

Leave a Reply