Jọkẹ Amọri
Nitori pe gbogbo awọn to yẹ ko sọ ọ ko le sọ ọ, mi o si mọdi ti wọn ṣe kọ lati sọrọ ni mo ṣe n fi gbogbo ẹnu sọ ọ fun yin pe ijọba mi ti ṣe daadaa. Ninu owo ti ko to nnkan ti a n ri naa la ti n gbe nnkan rere ṣe, ti a si n pese awọn ohun amayedẹrun tijọba PDP ti bajẹ lati ọdun 2015 ta a ti gbajọba.
Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari lo sọ eleyii di mimọ lasiko to n ba awọn alenulọrọ sọrọ niluu Owerri, nipinlẹ Imo, lasiko abẹwo ọlọjọ kan to ṣe si ipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Buhari ṣalaye pe oun lu ijọba oun lọgọ ẹnu pẹlu bi wọn ṣe gbogun ti ikọ afẹmiṣofo Boko Haram, ti wọn si ṣi wọn nidii lapa Oke-Ọya ati bi ijọba rẹ ṣe pese awọn ohun amayedẹrun ti ko lẹgbẹ fawọn araalu pẹlu bo ṣe jẹ pe ipo ti ko wojuu ri lawọn ba awọn ohun amayedẹrun gbogbo ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti bajẹ lọdun 2015 tawọn gbajọba.
Aarẹ Buhari ni alejo pataki ti Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodimma, fiwe pe lati waa ṣi oju ọna Owerri-Orlu Road, to jẹ abala akọkọ oju ọna Owerri-Okigwe Road ti wọn n kọ lọwọ. Bakan naa lo ṣi ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti ijọba ṣẹṣẹ tun kọ.
Buhari, ẹni ti gbogbo eeyan n wo tiyanu tiyanu pẹlu bi ọkunrin naa ṣe n rin kebekebe nigba to n lọọ ṣi iṣẹ akanṣe naa lu gomina Imo lọgọ ẹnu, o ṣi gboṣuba kare fun un pẹlu bo ṣe jẹ pe igba keji niyi ti yoo fiwe pe e lati waa ṣi awọn iṣẹ akanṣe to ti ṣe. O waa ṣeleri pe ijọba oun ko ni i kaaarẹ nipa pipese mundmundun ijọba awa-ara-wa fawọn araalu lai fi ti ẹgbẹ tabi ipinlẹ ti wọn ti wa ṣe.