Ijọba ti ko awọn ti Fulani ṣa ladaa n’Ibarapa lọ sileewosan UCH, n’Ibadan

Faith Adebọla

Ọjọ kẹrin lẹyin ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ṣeleri lati mojuto awọn ti Fulani ṣe leṣe lagbegbe Ibarapa lo mu ileri naa ṣẹ pẹlu bi ijọba rẹ ṣe lọọ ko awọn mẹta ti to fara gbọgbẹ lọwọ awọn janduku Fulani darandaran niluu Igangan lọ si oṣibitu ijọba apapọ, UCH, to wa n’Ibadan, fun itọju to peye.

Ọsan Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni ambulansi ileewosan naa waa ko awọn mẹtẹẹta, Ọgbẹni Oluwaṣeun Isaiah, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Adekọla Adeyẹmọ, ẹni ọdun marundinlọgọrin, ati baba agbalagba kan, Emmanuel Aderọgba, ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Gomina Makinde jẹjẹẹ lasiko abẹwo rẹ siluu Igangan latari bawọn Fulani darandaran ṣe n ṣakọlu sawọn Yoruba atawọn agbẹ lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, leyii ti fa rogbodiyan gidi nigba ti ajijagbara nni, Sunday Adeyẹmọ, waa le Seriki awọn Fulani, Salihu AbdulKadir, atawọn eeyan rẹ kuro niluu naa laipẹ yii.

Lasiko abẹwo naa ni wọn ti darukọ awọn mẹtẹẹta yii fun gomina, to si ṣeleri pe ijọba oun maa tọju wọn n’Ibadan, ati pe ọfẹ ni itọju ti wọn ba fun wọn, ijọba oun ni yoo sanwo rẹ, lati fi ẹmi ibanikẹdun rẹ han.

Ileewosan aladaani kan, Akintọla Hospital, to wa ni Opopona Akọya, l’ọja Oke-Ọla, lawọn tori ko yọ lọwọ iku ojiji naa ti n gba itọju tẹlẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla, oṣu to kọja, lawọn Fulani ṣakọlu si Isaiah nigba to n dari bọ latọna oko rẹ, ti wọn ṣa a ladaa yannayanna.

Iṣẹ alapako la gbọ pe Adeyẹmi n ṣe ni tiẹ, ilẹ ṣu wọn sibi ti wọn ti lọọ la gẹdu lọjọ Tọsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu ki-in-ni, ni wọn ba sun si abule kan nitosi, ṣugbọn ohun ti wọn ko reti lo ṣẹlẹ lọganjọ oru nigba tawọn Fulani buruku naa ya bo wọn ni nnkan bii aago meji, ti wọn si ṣa a ladaa lori. Atigba naa lo si ti n gba itọju lọsibitu kan.

Wọn ni oko ni ẹni kẹta wa, ti baba agbalagba naa fi kiyesi Fulani kan to n gba apa ibi ti ko yẹ ninu oko rẹ, lo ba sọ fun Fulani naa pe ko ma gba ibẹ. Lẹyin eyi, Fulani naa tun beere ọrọ lọwọ baba agbalagba ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin yii lai mọ pe Fulani naa fẹẹ ṣe oun ni jamba, ni, lo ba gbe ada le baba onibaba lataari.

Ṣa, wọn ti ko awọn mẹtẹẹta naa, atawọn mọlẹbi wọn diẹ, kan to maa duro ti wọn lọsibitu lọ.

Leave a Reply