Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ikọ Amọtẹkun labẹ idari Ọgagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ ti mu ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan ti wọn fura si bii ajinigbe niluu Ifaki-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido/Osi, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ọgagun-fẹyinti Kọmọlafẹ ṣalaye pe lasiko tawọn ikọ naa n lọ kaakiri ni wọn ri ọmọkunrin naa to jade lati inu igbo pẹlu aṣọ ṣọja, nigba ti wọn si mu un lo jẹwọ pe ajinigbe loun, oun ki i ṣe ṣọja rara.
Adari Amọtẹkun ọhun ni ọmọkunrin to kọkọ pe ara ẹ ni Adebayọ Damọla ko too sọ pe Emmanuel Tunde loun n jẹ ọhun sọ fawọn to mu un pe ilu Ọyẹ-Ekiti loun n gbe, ṣugbọn ọmọ ipinlẹ Kogi loun.
Kọmọlafẹ ni, ‘Nigba tọwọ tẹ ẹ, o ni ọmọ ipinlẹ Kogi loun, iṣẹ fọganaisa loun si n ṣe niluu Ọyẹ-Ekiti. Bakan naa lo ni Ado-Ekiti gangan loun ti n bọ, nibi toun ti lọọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo lọdọ ikọ Man O War.
‘Iwadii wa fidi ẹ mulẹ pe Ifaki lo n gbe, nigba ta a si de yara ẹ la ba oriṣiiriṣii nnkan tawọn ṣọja n lo, eyi to sọ pe ọkunrin ologun kan niluu Eko ko foun.’
Ọgagun-fẹyinti naa waa sọ ọ di mimọ pe ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, gan-an ni Gomina Kayọde Fayẹmi yoo ṣefilọlẹ ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, ikọ naa si ti ṣetan lati gbogun ti ijinigbe, ipaniyan, idigunjale atawọn iwa ọdaran mi-in.
O bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn eeyan, bẹẹ lo ni wọn yoo gbadun ikọ ọhun nitori yoo fun araalu lominira lọwọ awọn to n da wọn laamu.
Nigba to n fesi si afurasi ajinigbe tọwọ tẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe loootọ lo ti wa lọdọ awọn, ẹka iwadii ọdaran (CID) ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa lo si wa lọwọlọwọ.