Jide Alabi
Iku abilekọ kan, Nikẹ Ọpẹifa, ti di ariyanjiyan bayii lori bi awọn eeyan obinrin naa ṣe n sọ pe ọkọ ẹ, Abayọmi Ọpẹifa, lo lu u pa, nigba ti ọmọ oloogbe ọhun, Oyinlọla Ọpẹifa, sọ fawọn mọlẹbi atawọn ọlọpaa pe niṣe ni iya oun gbe majele ti wọn fi n pa ẹfọn jẹ
Adugbo kan ni ti wọn n pe ni Bankọle, lẹgbẹẹ Iyana-Iyẹsi, niluu Ọta, ipinlẹ Ogun, ni wahala ọhun ti ṣelẹ lọwọ aṣaalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọse yii, ti wọn si ti gbe oku obinrin na si mọṣuari. Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ọkọ ẹ ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa ni Eleweran, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Ọrọ kan ni wọn sọ pe o ṣe bii ọrọ laarin oun ati ọkọ ẹ ki iṣẹlẹ ọhun too waye, nigba ti awọn mọlẹbi obinrin yii si gbọ pe ọmọ wọn ti ku, niṣe ni wọn gba teṣan ọlọpaa lọ, ti wọn si sọ pe ko gbe majele jẹ rara, ọkọ ẹ lo lu u pa.
ALAROYE gbọ pe ode ariya kan ni obinrin yii n mura lati lọ lagbegbe Mowe-Ibafo, nipinlẹ Ogun, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja. Wọn ni ẹgbọn ẹ ọkunrin lo n ṣenawo lọjọ naa. Ohun ti wọn lo si da wahala silẹ ni bi obinrin yii ṣe fẹẹ tete kuro nile, ṣugbọn ti ọkọ ẹ sọ pe o ṣe pataki ko dana ounjẹ fawọn ọmọ ẹ laaarọ ọjọ naa ko too le jade kuro nile.
Ọpẹyẹmi Ọpẹifa, aburo ọkọ obinrin to ku yii sọ fun ALAROYE pe ọrọ yii ni wọn jọ fa titi di bii aago mejila ọsan ki iya ọkọ, iyẹn mama awọn ti awọn jọ n gbe too da si i, ti obinrin yii si gba ode awọn mọlebi ẹ lọ.
O ni ko ṣeni to mọ pe ko pada dana ounjẹ ọhun fun awọn ọmọ ẹ, bẹẹ lo to aago marun-un irọlẹ ki awọn too mọ pe awọn ọmọ náà ko ti i jẹ nnkan kan.
Nibi ti wahala ọhun ti bẹrẹ niyẹn, iyẹn lọjọ Satide, ọjọ Abamẹta. Nigba ti yoo si fi di aarọ Sannde, ọjọ Aiku, ti Nikẹ pada sile, wọn ni Abayọmi Ọpẹifa to ti figba kan ṣiṣẹ ni ileetura Eko Hotel, yari kanlẹ pe iyawo oun ko ni i wọle, ko pada sọdọ awọn mọlẹbi ẹ to ti n bọ.
A gbọ pe nibi ti wọn ti n fa ọrọ yii mọra wọn lọwọ lobinrin yii ti mu foonu ẹ, to si pe awọn obi ẹ, awọn yẹn ni wọn pe iya ọkọ lati fẹjọ sun un pe ọkọ ọmọ awọn ko jẹ ko wọle.
Wọn ni bi iya ọkọ ṣe da sọrọ ọhun niyẹn, ti wọn si sọ fun Abayọmi pe ti ko ba ti gba ki iyawo ẹ wọle, niṣe lawọn naa maa kuro nile naa fawọn mejeeji. Ọrọ yii ni wọn lo mu un gba iyawo ẹ laaye, to fi raaye wọle.
Ọpẹyẹmi to ba wa sọrọ sọ pe ni gbogbo ọsan ọjọ Sannde yẹn loun naa wa nile, ti ko si si wahala kankan mọ lẹyin ti wọn ti ba wọn da si i.
O ni ibi iṣẹ loun wa ti oun ti gba ipe rẹpẹtẹ lori foonu oun lẹyin ti oun ti kuro nile ni toun. Nigba ti oun si pe pada ni wọn ni ki oun maa bọ wale, Iya Oyin ti gbe majele jẹ, iyẹn lọjọ Aiku, Sannde.
Ọmọkunrin yii sọ pe ọkan ninu awọn ọmọ oloogbe yii, iyẹn Oyin, to to ọmọ ọdun mọkanla toun naa wa nibẹ nigba ti iya ẹ wọle sọ pe bi mama oun ṣe wọle lo tẹ ọmọ ẹ kekere silẹ, iyẹn abigbẹyin ti orukọ ẹ n jẹ Emmanuel, bo ṣe ṣe bẹẹ tan lo ni iya oun sọ pe Oyin, tọju awọn aburo ẹ, bẹẹ lo gba inu sọọbu ẹ lọ, ti oun naa si tẹle e.
O ni nibẹ ni mama oun ti gbe oogun apẹfọn to maa n ta, to si ja a. Nibi to ti fẹẹ gbe e mu ni ọmọ yii ti fariwo bọnu pe ‘maami ẹ ma mu snipper’, ariwo yii ni wọn lo pa lọ sọdọ baba ẹ, ki wọn too de lo ti mu un, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu lalẹ ọjọ Sannde ọhun.
O ni loju ẹsẹ ni wọn bẹrẹ si tọju ẹ, ṣugbọn nigba ti yoo fi di aarọ Mọnde, ọjọ Aje, obinrin naa ti ku.
Ọpẹyẹmi Ọpẹifa sọ pe, “Ohun tawọn mọlẹbi ẹ n sọ yẹn, niṣe ni wọn fẹẹ fi ko ba ẹgbọn mi. Ki i ṣe pe wọn ti wọn mọta lẹyin igba ti wọn ti ba wọn pari ẹ, ninu ile ni mo ti ba wọn lọsan-an nigba ti mo ti ṣọọṣi de. Aṣọ leesi funfun ni wọn wọ lọ sode, nigba ti emi si de, ankara ni mo ba lọrun wọn, ṣe ti wọn ko ba jẹ ki wọn wọle rara, bawo ni wọn ṣe fẹẹ paarọ aṣọ, koda mo tun ba wọn ṣawada nigba ti mo wọle.”
O fi kun un pe aarọ ọjọ Sannde lobinrin naa de, ati pe loootọ ni wọn da ọrọ bi ko ṣe dana ounjẹ silẹ fun awọn ọmọ ẹ ko too jade silẹ, ṣugbọn ti obinrin naa fi ibinu lọọ rojọ fun baba kan laduugbo naa ti wọn n pe ni Baba Kama.
Ẹjọ ọkọ to lọọ fi sun yii lo sọ pe Abayọmi binu si pe ṣe awọn ko le yanju wahala inu ẹbi awọn nile ni lai pe araadugbo si i. O ni ko pẹ pupọ ti gbogbo wahala ọhun fi rọle, ti oun si gba ibiiṣe lọ ni toun.
Lọwọ aṣaalẹ ti ọkọ obinrin yii tan ina jẹnẹretọ ni wọn sọ pe wọn too ṣi ṣọọbu obinrin naa nibi to ti n ta oriṣiiriṣi nnkan. Lasiko ti ọmọ ẹ to dagba ju, iyẹn Oyin, ṣi i, ti baba ẹ ni ko lọọ pa ina ara firiiji, ni wọn sọ pe Nikẹ naa wọnu ṣọọbu ọhun, to si mu ọkan lara majele apẹfọn to n ta, to si tu u mu loju ọmọ ẹ nibẹ naa.
Ọkan lara awọn aburo obinrin to ku yii, Pamilẹrin Adegoke, to maa n gbe ọrọ sori ikanni ayelujara daadaa ti sọ pe niṣe ni ọkọ aunti oun lu u pa, nitori to wa sode mọlẹbi.
Bakan naa ni Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye. O ni ọkunrin naa fi to awọn ọlọpaa leti pe iyawo oun gbe majele jẹ, ati pe loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti lọ sibẹ, ti wọn ya aworan ẹ, ti wọn si ti gbe oku ẹ lọ si mọṣuari. O ni lẹyin igba naa ni awọn mọlẹbi iyawo ọhun de, ti wọn sọ pe irọ ni Abayọmi n pa, niṣe lo lu u pa, nitori ija kekere to waye laarin wọn.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ọkunrin naa ti wa lahaamọ bayii, nibi to ti n sọ ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an.
O to bii ọdun mẹtala ti wọn sọ pe Abayọmi Ọpẹifa ati iyawo ẹ yii, Nikẹ, ti wọn pe ni ọmọ Ṣẹpẹtẹri, nipinlẹ Ọyọ, ti ṣegbeyawo, ti wọn ti jọ n gbe bii tọkọ-taya, ti wọn si bimọ mẹrin funra wọn. Awọn ọmọ naa ni: Oyinlọla, Michael, Samuel ati Emmanuel ti ko ju ọmọ ọdun meji lọ.