Ile akọku ni Ismaila tan ọmọọleewe kan lọ to ti fipa ba a lo pọ n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Magistreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo ti paṣẹ pe ki wọn ju birikila kan, Ibrahim Ismaila, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, sọgba ẹwọn Oke-Kura, fẹsun pe o fiba ba ọmọ ileewe ẹni ọdun mẹẹẹdogun lo pọ nibi ile akọku kan niluu Ilọrin, lẹyin to tan an lọ sibẹ.

Agbefọba, Gbenga Ayẹni, sọ fun kootu pe lasiko ti akẹkọọ naa ti wọn fi orukọ bo laṣiiri n bọ lati ileewe ni Ismaila da a lọna, o tan an lọ si ile akọlu kan, o si fi tipatipa ba a lo pọ. O tẹsiwaju pe adajọ fi Ismaila ati ẹni keji rẹ, Abdurasheed Yusuf, si ọgba ẹwọn tori pe Yusuf wa nibẹ nigba ti Ismaila ṣiṣẹ aburu naa, ti ko si da a lẹkun.

Adajọ Muhammed Dasuki paṣẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi mejeeji lọ si ọgba ẹwọn Oke-Kura, o sun igbẹjọ si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ọdun 2023 yii.

 

Leave a Reply