Ile akọku ni Jamiu mu ọmọ ọdun mẹsan-an lọ n’llọrin, o si fipa ba a laṣepọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọwọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi ipinlẹ Kwara ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Jamiu Akande, lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ kekere kan lo pọ.

Agbegbe Pàkátà, niluu Ilọrin, la gbọ pe Jamiu, ti n fipa ba ọmọdebinrin yii lo pọ lẹyin to ba ti ranṣẹ pe ko lọọ ra burẹdi wa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ ṣifu difẹnsi ni Kwara, ASC Ayọọla Michael Shọla, fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Jamiu Akande, ẹni ọdun mọkandinlogun, to fipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an kan lo pọ lagbegbe Pàkátà, niluu Ilọrin.

O tẹsiwaju pe Arabinrin kan, Alaaja Yusuf Mariam Jọkẹ, to n gbe ni Agboole Bàbárèké, lagbegbe Ìpàta-Ọlọ́jẹ̀ẹ́, niluu Ilọrin, lo mu ẹsun lọ si ọfiisi ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin nipinlẹ Kwara, Ministry of Women Affairs), lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, pe Jamiu ti fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹsan-an kan laṣepọ ni ile-akọku kan lẹyin to fi burẹdi tan an.

Ayọọla ni eyi lo ṣokunfa bi wọn ṣe lọọ mu Jamiu, to si jẹwọ pe loootọ ni oun n ṣe yunkẹ-yunkẹ pẹlu ọmọdebinrin naa.

O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, ireti si wa pe yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ

Leave a Reply