Lasiko ti awọn ọmoogun Yoruba Nation n fara han ni kootu lọwọ, eyi lohun ti Makinde ṣe fun Dupẹ Onitiri n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti awọn ajijagbara Yoruba Nation ti dero ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Gomina Ṣeyi Makinde, ti wo ile ọga awọn afurasi aditẹgbajọba naa,  Oloye Dupẹ Onitiri lulẹ.

Ile ọhun, to wa laduugbo Fátúsìn, nigboro Ibadan, lo jẹ ti Abilekọ Dupẹ Onítìrí-Abiọla ti i ṣe iyawo oloogbe M.KO. Abiọla, ẹni to wọle idibo aarẹ orileede yii lọdun 1993, ṣugbọn ti ijọba ologun, labẹ akoso Ọgagun Ibrahim Babangida, fagi le idibo naa.

Inu ile ti obinrin yii ti ṣe ikede rẹ ọhun naa la gbọ pe awọn ọmọogun aditẹgbajọba rẹ ti dihamọra, ti wọn fi ṣigun lọ sile ijọba ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Abamẹta, Satide, to koja, nibi ti ọfiisi gomina ipinlẹ ọhun wa, wọn lawọn yoo gba ijọba ni dandan.

Lọjọ yii kan naa ni Dupẹ Onítìrí-Abiọla kede ninu ile ẹ yii, pe ẹya Yoruba ko si lara Naijiria mọ, wọn ti da duro gẹgẹ bii orileede kan lọtọ laaye ara wọn, ati pe Democratic Republic of Yoruba, iyẹn ilẹ Olominira Yoruba lorukọ ti orileede tuntun naa n jẹ.

Awọn ọmoogun aditẹgbajọba ọhun ya wọ inu ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ti gbakoso ibẹ, awọn ọlọpaa pada le wọn jade, wọn si mu mọkandinlọgbọn (29) ninu awọn eeyan naa pẹlu iranlọwọ awọn ọmọ-ogun orileede yii atawọn ileeṣẹ agbofinro mi-in bii Amọtẹkun, Sifu Difẹnsi, Operation Burst, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun (17), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ gbe wọn lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, ti Onidaajọ O.O. Ogunkanmi, si paṣẹ pe ki wọn lọọ tọju awọn eeyan naa si ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, titi di ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ti igbẹjọ ọhun yoo bẹrẹ gan-an.

Bi awọn afurasi ọdaran naa ṣe n fara han lọwọ ni kootu, lawọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ n bi ile awọn ọmoogun ọlọtẹ naa lulẹ pẹlu katakata, ti wọn ṣi ni ilẹ naa ti di ti ijọba.

Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣapejuwe awọn to fẹẹ gbajọba mọ ọn lọwọ naa gẹgẹ bii agbesunmọmi, to si kede  gbogbo awọn to n ṣatilẹlẹyin fun wọn gẹgẹ bii afurasi ọdaran ti ijọba n wa lati mu.

Leave a Reply