Ile alaja mọkanlelogun to wo: Gomina Sanwo-Olu gbe igbimọ oluwadii dide

Jọkẹ Amọri

Lati dena iru ijamba bẹẹ lọjọ iwaju, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide-Sanwoolu, ti gbe igbimọ oluwadii kan dide lati tuṣu desalẹ ikoko lori ohun to fa a ti ile alaja mọkanlelogun ti wọn n kọ ni Ikoyi, nipinlẹ Eko, yii fi da wo.

Igbimọ oluwadii ẹlẹni marun-un ti wọn yoo jọ ṣiṣẹ iwadii naa ni Tajudeen Adebanjọ, Precious Igbowelundu, Oyebọla Owolabi, Halima Balogun ati Faidat Ahmed.

Awọn ọmọ igbimọ naa ni Aarẹ ẹgbẹ awọn to n ṣaato ilu, Nigeria Institute of Town Planners, Tayọ Ayinde, Alaga, Ekundayọ Ọnajọbi (Akọwe), Idris AkintilỌ, Yinka Ogundairo, Godfrey O. Godfrey ati Abilekọ Bunmi Ibrahim.

Ọgbọn ọjọ, iyẹn oṣu kan, ni igbimọ naa yoo fi jokoo lati ṣiṣẹ iwadii yii.

Gomina naa ni gbogbo awọn ti aje iwa buruku ba ṣi mọ lori lori ọrọ ile naa ko ni i lọ lai jiya. O fi kun un pe titi Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ijọba yoo kan si awọn ti awọn eeyan wọn ku nibẹ lati waa da wọn mọ, ki wọn le ṣayẹwo si awọn oku naa.

Bẹẹ lo ni ko ṣee ṣe lati mọ iye eeyan to wa labẹ ile naa nitori ko si akọsilẹ kankan to fi eleyii han yala latọdọ awọn to n kọle ni tabi awọn agbaṣẹṣe.

Sanwoolu kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ti eeyan wa ninu ijamba naa. O ni gbogbo awọn ti awọn ba tun gbọ pe wọn ṣe ohun to ku diẹ kaato lori ọrọ ile naa ni oun yoo fi jofin.

Leave a Reply