Florence Babasola, Oṣogbo
Wahala ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ọṣun tun gba ọna mi-in yọ lọsan-an ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nigba ti ile-ẹjọ giga kan niluu Ikirun sọ pe ofo ọjọ keji ọja ni igbesẹ ẹgbẹ naa lati yọ Ọnarebu Ọlasọji Adagunodo nipo alaga wọn.
Loṣu diẹ sẹyin lawọn ọmọ ẹgbẹ kan kọ iwe ifẹhonu han lọ sọdọ awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa l’Abuja, wọn ni awọn ko fẹ Adagunodo nipo mọ, wọn ni o n ṣe owo awọn baṣubaṣu, ati pe ki i gba imọran.
Bakan naa ni diẹ lara awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ naa l’Ọṣun sọ pe awọn ko nigbagbọ kikun ninu rẹ mọ, wọn ni o n ṣoju meji ninu ẹgbẹ, awọn ara Abuja si kọwe pe ki Adagunodo yẹba fun igba diẹ lati ṣewadii lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ati pe ki igbakeji rẹ, Sunday Atidade, maa dele fun un.
Lasiko yẹn, Adagunodo kọwe pada sọdọ awọn igbimọ oluṣakoso ẹgbẹ wọn l’Abuja, o ni ọtẹ ni gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ, ati pe awọn alagbara kan lati ilu Ẹdẹ ti wọn mọ pe oun ki i ṣabosi lori ohunkohun ni wọn fẹẹ le oun kuro nipo. O ni oun fẹ ki wọn ṣewadii daadaa lọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ, ki wọn le fidi ododo mulẹ.
Ṣugbọn lojiji ni lẹta wa lati Abuja pe wọn yọ ọkunrin naa nipo alaga, wọn si fi akọwe ipolongo ẹgbẹ naa tẹlẹ, Sunday Bisi, rọpo rẹ, Atidade si pada sipo igbakeji rẹ.
Idi niyi ti Adagunodo fi gba kootu lọ, o ni awọn igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa, labẹ alaga wọn, Uche Secondus, ko gbe igbimọ oluwadii kalẹ lati gbọ awijare toun lori gbogbo ẹsun ti awọn perete fi kan oun.
Ninu idajọ oloju-ewe mẹta naa, Onidaajọ Jide Falọla sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP gbe igbesẹ to lodi si ofin ẹgbẹ naa nipa pe wọn ko gbọ ọrọ ẹnu Adagunodo ti wọn fi kede idaduro rẹ, o ni iwa to buru gbaa ni.
Gbogbo ibeere mejeeje ti Adagunodo gbe lọ nile-ẹjọ tẹwọ gba. Adajọ ni ki Sunday Bisi kuro nipo alaga loju-ẹsẹ, ki Adagunodo si pada sipo rẹ, lai ṣe bẹẹ, a jẹ pe ẹgbẹ naa n foju di ile-ẹjọ niyẹn, ti wọn yoo si ri pipọn oju ofin.
Ni bayii, Sunday Bisi ti sọ pe awọn agbẹjọro oun yoo bẹrẹ akiyesi idajọ naa lati mọ igbesẹ to ku, bẹẹ ni Adagunodo naa n sọ pe idajọ naa ti fidi ododo mulẹ, o si ti tun igbẹkẹle awọn araalu ninu ẹka eto-idajọ ṣe pupọ.