Ile-ẹjọ fiwe ti yoo pọn ayẹwo ẹjẹ ọmọ Mohbad ni dandan ranṣẹ si Wumi

Faith Adebọla

Ni bayii, dandan lowo-ori, ọran-an-yan laṣọ ibora, lọrọ ayẹwo ẹjọ Liam, da fun Wumi, iyawo gbaju-gbaja onkọrin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad to doloogbe lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 to kọja. Ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fun obinrin naa niwee-aṣẹ lati gba iyọnda ki wọn ṣayẹwo ẹjẹ DNA fọmọ rẹ, Liam, lojuna ati le fidi ododo mulẹ boya Mohbad ni baba ọmọ naa loootọ abi ki i ṣe bẹẹ.

Ninu atẹjade kan ti Amofin Monisọla Odumosu, iyẹn agbejọro to n ṣoju fun mọlẹbi Alọba fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin yii, lo ti sọrọ ọhun di mimọ.

Ninu ẹbẹ kan ti Alagba Joseph Alọba, Baba Mohbad, bẹ ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Ikorodu, o ni kile-ẹjọ gba oun laaye lati lọọ lẹ iwe aṣẹ kootu lori ayẹwo ẹjẹ ọhun mọ ile tawọn ti mọ Wumi mọ latilẹ, tori bii ẹẹmeji ọtọọtọ ni oniṣẹ kootu ti n fi iwe naa wa a kiri, amọ ti wọn ko ri i, ko si sẹni to mọ ibi to n gbe bayii, bẹẹ ni wọn ko ri ẹni ti wọn le fi iwe naa ran si i.

Amofin Emmanuel Oroko, to lewaju awọn amofin yooku ti wọn n ṣoju fun mọlẹbi Alọba sọ pe, niwọn igba ti ile-ẹjọ ba ti fọwọ si i pe ki wọn lọọ lẹ iwe aṣẹ ọhun mọ ara ogiri adirẹsi Wumi to wa lọwọ, eyi yoo jẹ ki obinrin naa mọ pe o di dandan f’oun lati yọnda ara rẹ ati ọmọ ọwọ rẹ silẹ fun ayẹwo ẹjẹ Deoxyribonucleic,ti wọn n pe ni DNA, eyi ti yoo sọ pato ẹni ti baba ati iya ọmọ naa i ṣe. Ile-ẹjọ Majisreeti si ti fountẹ jan ẹbẹ naa bayii.

Ẹ oo ranti pe ọkan lara awọn awuyewuye to n ja ranyin lori ayelujara nipa Mohbad ni bawọn kan ṣe n gbe e pooyi ẹnu pe ọmọ Wumi, Liam, ki i ṣe ti Mohbad. Eyi lo mu kawọn mọlẹbi Alọba pe ẹjọ si ile-ẹjọ akanṣe kan niluu Ikorodu, nibi ti wọn ti n mojuto ọrọ to jẹ mọ idile, pe ki wọn paṣẹ ṣiṣe ayẹwo ẹjẹ fun Liam, awọn fẹẹ ri okodoro ibi ti ọmọ naa ti ṣẹ wa.

Ọrọ ayẹwo ẹjẹ yii wa lara ohun ti Baba Mohbad sọ laipẹ yii pe o fa a toun ko fi ti i fọwọ si i ki wọn sinku ọmọ oun latigba tawọn ọlọpaa ti lọọ hu oku naa lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun to kọja, fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣokunfa iku to pa a lojiji.

Leave a Reply