O tan! Portable ko Olori Alaafin tẹlẹ, Queen Dami, sita bii ọmọ ọjọ mẹjọ

Monisọla Saka

Gbajumọ olorin taka-sufee tẹnu ki i sin lara rẹ, Habeeb Okikiọla Ọmọ Ọlalọmi Badmus, tawọn eeyan mọ si Portable Zaazu Zeh, ti tun gbe tuntun de. Lọtẹ yii, obinrin tuntun to wa loju ọpọn, tawọn eeyan si ka si ẹyinloju ẹ lẹyin Bẹwaji to jẹ ojulowo iyawo ile ẹ, Olori Damilọla to jẹ Ayaba Alaafin Ọyọ to waja ni Portable ko sita bii ọmọ tuntun.

Niṣe ni ọkunrin to maa n pariwo, ‘wahala wahala wahala’ yii n ba a fa wahala lori ayelujara, nitori ti tọhun ko ti i bimọ fun un. Afi bii pe ọkunrin to n pera ẹ ni bukata ijọba apapọ yii ti rẹro ọrọ naa sinu tẹlẹ, nitori pẹlu itara lo fi kọ gbogbo awọn ọrọ yii si abẹ fọto ti obinrin naa gbe soju ayelujara.

Portable ni pẹlu gbogbo itọju ati inawo oun lori ẹ, arungun ni Dami fẹẹ ya pẹlu bo ṣe kọ lati bimọ fun oun. Ọmọkunrin olorin yii ni Dami to n bu oun pe ọdọọdun loun n bimọ lo kọ ti ko loyun depo pe yoo bimọ foun yii.

Dami lo kọkọ tana wa ọrọ lọdọ Portable pẹlu bo ṣe kọ ọrọ si abẹ fọto rẹ pe, “ọmọ to n dan”, ni Zaazu naa ba da a lohun pe, “Mo tọju ẹ nigba ti ko si ẹnikẹni lati duro ti ẹ. Mo fi ifẹ han si ọ. O wa labẹ orule mi, amọ oju rẹ ṣi wa nita. O ba mi loju jẹ gan-an o. O ni mo n bimọ lọdọọdun, ki lo de ti o ò waa fẹẹ bimọ fun mi?

Esi ti Dami kọkọ kọ si i bo ṣe n fibinu sọrọ ni pe ko mura si i.

Ẹrin arintakiti lawọn eeyan ori ayelujara n fi Portable rin.

Wọn ni ojoojumọ ni ara maa n waye ninu idile rẹ.

Ọpọlọpọ lo n kan saara si Dami, wọn loun nikan lo ni laakaye ninu gbogbo awọn obinrin to n ko kiri. Bẹẹ lawọn kan n sọ pe ko ma yọ rọba ifeto sọmọ bibi to wa lara ẹ. Wọn ni to ba ti fi le bimọ fun Portable pẹrẹ, o ha niyẹn, tiẹ si ba a niyẹn, nitori oun naa maa kun awọn obinrin yooku to n figba gbogbo han leemọ labẹnu ati lori ayelujara ni.

Ọrọ buruku lawọn kan sọ si Dami, wọn ni gbogbo ẹsin ti Portable ba fi i ṣe, gbogbo ohun toju ẹ ba ri, oun lo fa a, nitori o mọ pe ẹnu jagunlabi ko bo ko too lọọ fira ẹ wọlẹ lọdọ rẹ.

Wọn ni eeyan to tiẹ ti le kọkọ fi ẹgbẹ baba baba ẹ ṣe ọkọ, ki lohun to tun ku.

Gbogbo iyi ati apọnle to wa lara ẹ gẹgẹ bii olori iku baba yeye, ni wọn ni o ti fi yi ẹrẹ̀ lọdọ Portable.

Awọn kan tun ni ọrẹkunrin ni Portable yẹ fun, ki i ṣe ọkọ gidi, ko si le ṣe iṣe ọkọ gidi. Wọn ni ọkunrin naa ko laṣiiri, ẹnikẹni to ba fẹẹ ba a da nnkan pọ ni ọna yoowu si gbọdọ ṣọra.

Bayii ni kaluku n sọ tiẹ, ti wọn si ki Dami naa kaabọ si aarin awọn ti Portable ti tu yẹri wọn nita gbangba, ti yoo si tun maa patẹ wọn sori afẹfẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun to kọja ni aṣiri tu sita pe ọmọbinrin to ti figba kan jẹ Olori laafin Ọba Adeyẹmi to waja yii ati Portable jọ n jẹ iṣẹ ara wọn. Ọmọbinrin ti wọn n pe ni Queen Dami yii naa ko fi bo rara, nitori ni gbogbo igba lo maa n gbe fọto Portable sita, ti yoo si kọ ọrọ oriṣiiriṣii nipa rẹ.

Ṣugbọn ko sẹni to mọ pe ọmọkunrin olorin ti wọn n pe ni Zah Zuh Zeh yii ti gbale fun Dami, to si ti n ṣe aya lọọdẹ Portable, afi bi Ọlalọmi ṣe tu aṣiri ọmọbinrin naa jade pẹlu bo ṣe n pariwo pe ko bimọ foun, pẹlu gbogbo bi oun ṣẹ n tọju rẹ to.

 

Leave a Reply