Adeleke buwọ lu ami idanimọ tuntun fun ipinlẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina Ademọla Adeleke ti buwọ lu ofin to ṣagbekalẹ ami idanimọ tuntun fun ipinlẹ Ọṣun.

Ni saa akọkọ iṣejọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla lo mu ayipada ba ami idanimọ tipinlẹ Ọṣun ti n lo lati ọdun 1991.

Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, to si ti di fa-n-fa-a laarin awọn ẹgbẹ oṣelu, ṣugbọn ami idanimọ naa ni ẹni to gbejọba fun, Adegboyega Oyetọla, naa lo fọdun mẹrin.

Lẹyin ti Adeleke gbajọba lo kede pe oun fagi le awọn igbesẹ kan tijọba APC gbe, lara rẹ ni ami idanimọ yii ati bi Arẹgbẹṣọla ṣe yi orukọ Ọṣun pada kuro ni Osun State si State of Osun.

Laipẹ yii nile-igbimọ aṣofin gbe aba kan jade pe ṣe ni kijọba Ademọla Adeleke naa ṣagbekalẹ ami idanimọ tuntun fun ipinlẹ Ọṣun.

Lẹyin ti wọn ka aba naa nileegbimọ aṣofin, ti gbogbo wọn si fọwọ si i, ni Gomina Adeleke buwọ lu u l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, ọsu Kẹrin, ọdun yii.

Adeleke fi idunnu rẹ han lori ami idanimọ tuntun ọhun, o ni aworan naa kun fun ọgbọn ati imọ ijinlẹ fun awọn iran to n bọ.

O ni o sọ ohun gbogbo nipa ipinlẹ Ọṣun, lati ori ọdun ti wọn da a silẹ, si awọn nnkan alumọọni to wa nibẹ, pẹlu ibaṣepọ to wa laarin gbogbo ẹkun mẹtẹẹta to wa l’Ọṣun.

Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Olori ile, Ọnarebu Adewale Ẹgbẹdun, ṣapejuwe igbesẹ nini ami idanimọ tuntun naa gẹgẹ bii eyi to tọ lasiko yii.

Ẹgbẹdun ṣalaye pe gbogbo igbesẹ ti yoo maa mu ki ipinlẹ Ọṣun goke agba lawọn aṣofin yoo maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ iṣejọba lati gbe.

 

Leave a Reply