Ẹ la awọn araalu lọyẹ ki ẹ too maa mu wọn fun ẹsun ṣiṣe Naira baṣubaṣu-Oluwoo  

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Pẹlu bi ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo araalu baṣubaṣu, EFCC, ṣe n ko awọn eeyan bayii lori ẹsun pe wọn n ba owo Naira ilẹ wa jẹ, Oluwoo ti ilu Iwọ, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe o yẹ ki ilanilọyẹ ṣaaju igbesẹ ajọ EFCC yii.

Ọba Akanbi ni pupọ awọn ọmọ orileede yii ni ko ni oye ofin ti wọn gbe jade lori ibi wọn ṣe le maa na owo Naira lode, ko si ṣee ṣe fun eeyan lati gbọn ju nnkan ti ko ba mọ lọ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin fun Kabiesi, Alli Ibraheem, gbe jade ni Oluwoo ti sọ pe o yẹ ki ajọ naa kọkọ ṣe ilanilọyẹ to rinlẹ lori awọn iwe iroyin, ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ati ileeṣẹ amohunmaworan kaakiri orileede yii lori ofin naa, ki wọn to maa fi pampẹ ofin mu awọn araalu.

Ọba Akanbi woye pe fifi owo mọ eeyan lori jẹ aṣa to wọpọ laarin iran Yoruba ati Ibo, paapaa lasiko ayẹyẹ igbeyawo, ikomọjade ati isinku agba, o si ti wa lati ọjọ to ti pẹ.

O ni ẹmi kan lo maa n mu ori awọn eeyan ẹya mejeeji yii wu nibi inawo ti wọn ba ti gbọ ilu tabi orin, ṣugbọn ti ipolongo lodi si i ba ti dunlẹ daadaa, onikaluku yoo ki ọwọ ọmọ rẹ b’aṣọ.

Ọba Akanbi sọ siwaju pe bii igba teeyan n fi iya aimọdi jẹ araalu ni ti ajọ naa ko ba kọkọ ṣedanilẹkọọ lori ofin to de nina owo nibi inawo atawọn ijiya to rọ mọ ọn.

O ni ti ajọ EFCC ba ti ṣe eleyii, wọn yoo lanfaani lati maa fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni ti ajere iwa ibajẹ yii ba ṣi mọ lori lai ni idalẹbi kankan ni ọkan tiwọn gan-an.

Oluwoo gboṣuba fun ajọ EFCC fun oniruuru aṣeyọri ti wọn n ṣe bayii lorii gbigba obitibiti owo ti awọn wọbia adari kan ti ko jẹ pada sapo ijọba.

Leave a Reply