Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Odidi mọto mẹta, ile kan ati foonu olowo nla mẹta nijọba ti gbesẹ le bayii, ọwọ ọmọ ‘Yahoo’ kan, Kọmọlafẹ Ọlọlade Ọlajide, ẹni ọgbọn ọdun, to kawe jade ni yunifasiti ipinlẹ Ọṣun ni wọn ti gba a.
Ẹsun ti wọn ka si Kọmọlafe lẹsẹ ni pipe-ara-ẹni lohun ti a ko jẹ lori ayelujara.
Ajọ EFCC, ẹka Ibadan, lo mu Kọmọlafẹ lọjọ kejilelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lẹyin ti iwadii wọn fi han pe onijibiti ni lori ayelujara.
Oun naa jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun jibiti ati ‘Yahoo’ ṣiṣẹ.
Eyi lo jẹ ki Adajọ Mohammed Abubakar, ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Abẹokuta, paṣẹ pe ki Kọmọlafẹ lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (300, 000).
Yatọ si idajọ ẹwọn yii, Adajọ Abubakar paṣẹ pe ki ọmọkunrin yii da owo to le ni miliọnu kan naira to feru gbe jade pada.(1,319, 708.85k).
Awọn mọto meta ti i ṣe Toyota Corolla (2008 model), Toyota Venza (2013 model) ati Toyota Camry (2013 model) ni kootu gbẹsẹ le, awọn mọto ti Kọmọlafẹ fi owo jibiti to lu awọn eeyan ra ni.
Bakan naa ni wọn ni ijọba ti gbẹsẹ le foonu mẹta to n lo, awọn foonu naa ni: iPhone 12, Samsung S5 ati Samsung Galaxy S6, wọn tun gba eyi ti wọn n pe ni Macbook lọwọ rẹ pẹlu.
Ile kan ti ọkunrin yii kọ lati ara jibiti lilu naa wa ninu ohun tijọba gba lọwọ ẹ, ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti kọ akọle sara ile naa, eyi to n tọka si i pe tijọba ni i ṣe bayii.