Faith Adebọla
Ile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja ti kede lọjọ Ẹti, Furaidee yii, pe ko siyatọ ninu ọmọ to n jẹ eeru ateyi to n jẹ yẹẹpẹ, adape ole ni ka sọ pe ọmọ n fẹwọ, o ni orukọ to ba iwa tawọn janduku agbebọn n hu mu ni lati pe wọn ni afẹmiṣofo eeṣin-o-kọku ẹda, o si kede wọn bẹẹ.
Ṣe ṣaaju asiko yii lọgọọrọ eeyan ti gba ijọba apapọ ati Aarẹ Muhammadu Buhari lamọran lati kede awọn ọdaju ẹda to n huwa apaayan ati ijinigbe kaakiri orileede yii, paapaa lapa Oke-Ọya, gẹgẹ bii afẹmiṣofo, ki wọn si doju ogun kọ wọn bo ṣe yẹ, ṣugbọn ijọba ko ṣe bẹẹ.
Bakan naa ni agba ẹsin Musulumi lapa Oke-Ọya, Sheikh Abubakar Gumi, ti figba kan sọ pe o lewu lati pe awọn agbebọn ni afẹmiṣofo tabi eeṣin-o-kọ’ku, o ni araalu naa ni wọn, iya to n jẹ wọn lo n jẹ ki wọn maa ṣe ilu ni ṣuta ti wọn n ṣe.
Ṣugbọn lasiko igbẹjọ kan ti ileeṣẹ to n ba araalu ṣẹjọ, DPP, (Directorate of Public Prosecution), pe ta ko iwa buruku tawọn ẹgbẹ agbebọn meji ti wọn porukọ wọn ni Yan Bindiga ati Yan Ta’adda n hu, Adajọ Taiwo Taiwo tile-ẹjọ giga naa sọ pe oun gba ẹbẹ Ọga agba DPP, Ọgbẹni Mohammed Abubakar wọle, pe kile-ẹjọ kede ẹgbẹ naa bii ẹgbẹ afẹmiṣofo pọmbele.
Abubakar fẹsun kan awọn ẹgbẹ wọnyi pe wọn gbona ninu iwa ijinigbe, ipaayan, ifipabanilopọ, ilọnilọwọgba ati fifi ibọn ṣeni leṣe tabi ki wọn yinbọn paayan bii ẹran. Awọn ni wọn si wa nidii iru awọn iwa buruku bẹẹ to n waye lapa Ariwa/Ila-Oorun, Aarin-Gbungbun Ariwa ati awọn agbegbe mi-in lorileede yii.
Lara awọn iwa mi-in ti wọn tun n hu ni ijinigbe lati fi pawo, ijinigbe lati fi wọn ṣ’aya, jiji awọn ọmọleewe rẹpẹte gbe wọ’gbo, jiji maaluu ko, sisọ awọn eeyan di ẹru, sisọ awọn eeyan sahaamọ, pipọn awọn eeyan loju, didana sun dukia ati awọn iwa buruku bẹẹ.
Lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ yii ni ko sorukọ mi-in to yẹ lati pe awọn ẹgbẹ buruku wọnyi pẹlu awọn iwa ibi ti wọn n hu ju afẹmiṣofo ati eeṣin-o-kọ’ku lọ, o ni apanilaya ni wọn, ki ijọba si da sẹria to yẹ fun wọn.
“Ẹgbẹ Yan Bindiga, ẹgbẹ Yan Ta’adda, ati awọn ẹgbẹ bii eyi ti iṣẹ wọn jọra paapaa lapa Ariwa ilẹ wa jẹ ẹgbẹ afẹmiṣofo, eesin-o-kọ’ku ni wọn, ẹgbẹ wọn ko bofin mu, ko si lakọọlẹ ijọba, ẹgbẹ buruku ti wọn n foru boju huwa ibi ni wọn, ẹgbẹ ti a gbọdọ fofin de patapata ni.”
Adajọ Taiwo lo kede bẹẹ, o si paṣẹ pe kijọba apapọ tete polongo orukọ wọn ati ẹgbẹ wọn bii afẹmiṣofo kia.