Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti kọ lati gba beeli awọn afurasi mẹjọ ti wọn fipa ba akẹkọọ Fasiti Ilọrin, Ọlajide Blessing, lo pọ, ti wọn si tun ṣeku pa a, nile rẹ to wa ni agbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, latari pe mẹta ninu awọn afurasi ọhun kuna lati gba agbẹjọro fun ara wọn.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni Abdulazeez Ismail, Ajala Moses Oluwatimileyin (aka Jacklord), Kareem Oshioyẹmi Rasheed (Rashworld), Abdullateef Ọ̀mogbọlahan, Abdulkereem Shuaib (aka Easy), Abdullateef Abdulrahman, Dauda Bashir Adedayọ (aka Bashman) ati Akande Taiye Ọladẹjọ ni wọn wọ lọ siwaju Onidaajọ Ibrahim Yusuf, l‘Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọjá, lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara fidi ẹ mulẹ pe wọn gbimọ-pọ, wọn si fi tipatipa ba Ọlajide Blessing Omowumi lo pọ, ti wọn si tun ṣeku pa a, bakan naa, wọn tun fẹsun kan wọn pe wọn tun jale ninu ile oloogbe nigba ti wọn gba ẹmi rẹ tan.
Iwadii fihan pe, mẹta ninu awọn afurasi ọhun ni wọn jẹ alabaagbe Blessing, wọn lọọ ka a mọle, wọn fi aṣọ di i lẹnu, wọn bọ ọ sihooho, wọn si ba a lo pọ titi ẹmi fi bọ lara rẹ. Ni kete to ku tan ni wọn ji awọn eroja kan lọ ninu ile rẹ.
Lara awọn ohun ti wọn ji gbe ni ẹrọ ibanisọrọ Samsung A2 Cole, Ẹrọ kọmputa alagbeeka (laptop), maṣinni iranṣọ (sewing machine) ati ṣaja Infinix kan, wọn tun mu ATM kaadi rẹ, wọn fi gbowo ninu akaunti rẹ. Ẹrọ ibanisọrọ ti wọn jigbe ọhun ni wọn fi tọpinpin wọn de ọdọ awọn ti wọn ta awọn ẹrọ ibanisọrọ ati kọmputa naa fun ti ọwọ fi n tẹ wọn lọkọọkan.
Awọn mẹjẹẹjọ lawọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn, wọn si rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe ki wọn fun awọn lanfaani lati maa lọ sile, ṣugbọn Onidaajọ Ibrahim ko gba beeli wọn, o si sọ pe nitori awọn mẹta ti ko ni agbẹjọro, oun sun igbẹjọ naa si Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii.