Ile-ẹjọ ni ìjọba Ọṣun ko gbọdọ yan Olufọn tuntun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọṣun kan to fikalẹ siluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lori ọrọ yiyan Olufọn ti ilu Ifọn-Orolu tuntun.
Laipẹ lawọn idile to n jọba niluu naa pariwo sita pe awọn n gbọ finrinfinrin pe ijọba fẹẹ kede orukọ ẹnikan gẹgẹ bii Olufọn lai fi ti ẹjọ to wa ni kootu ṣe.
Ṣaaju, iyẹn ni oṣu diẹ sẹyin lawọn idile ọlọmọọba niluu Ifọn-Orolu ti wọ ara wọn lọ si kootu lati le mọ boya agbekalẹ ilana jijẹ ọba ilu naa ti ọdun 1979 tabi ti ọdun 1988 ni wọn yoo lo lati yan ọba tuntun.
Eleyii ni wọn si n fa lọwọ ti awọn afọbajẹ ko ṣe ti i lanfaani lati beere fun orukọ ọmọ-oye kankan latidile marun-un to n jẹ ọba ilu naa lati oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ti Ọba Magbagbeọla Olumoyero ti waja.
Amọ ṣa, nigba ti ẹjọ naa tun waye ni kootu lọṣe yii, awọn agbẹjọro fun olupẹjọ ati olujẹjọ ṣepade papọ (Pretrial conference) lori bi igbẹjọ naa yoo ṣe lọ.
Onidaajọ Adebiyi si sọ pe igbẹjọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹu lọjọ kọkandinlogun, ati ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun yii, o si paṣẹ pe kijọba ma ṣe ṣe ohunkohun lori ọrọ ọba ilu naa titi tigbẹjọ yoo fi pari.

Leave a Reply