Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ giga kan l’Abuja ti ni dandan ni fun ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii lati fi awọn iwe-ẹri ti Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, fẹẹ fi dije sita.
Agbẹjọro kan to filu Akurẹ ṣebugbe, Amofin Emmanuel Fẹmi Emadamori, lo lọ si kootu ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, to si ni ki adajọ pasẹ fun ajọ eleto idibo lati fi awọn iwe-ẹri Ọnarebu Ajayi sita gẹgẹ bii ilana ofin.
Ajafẹtọọ ọhun ni o da oun loju pe ayederu lawọn iwe-ẹri ti ọkunrin naa fi silẹ lọdọ ajọ eleto idibo.
Ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni Onidaajọ A. R. Muhammed gbe idajọ rẹ kalẹ, ninu eyi to ti fontẹ lu ibeere agbẹjọro naa, to si pasẹ fun ajọ eleto idibo lati fi awọn iwe-ẹri Ajayi sita lẹyẹ-o-ṣọka.
Nigba to n fi idunnu rẹ han fawọn oniroyin kan lori idajọ naa, Emodamori ni niwọn igba tile-ẹjọ ti fun oun laṣẹ lati ri awọn iwe-ẹri igbakeji gomina gba lọdọ ajọ eleto idibo, o ni igbesẹ ti oun n gbe lọwọ ni lati gbe ọkunrin naa lọ si kootu, ki wọn le yẹ aga mọ ọn nidii gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu ZLP, ni ibamu pẹlu abala mọkanlelọgbọn ninu iwe ofin eto idibo ọdun 2010.