Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ṣe ni Adeọla Adegboyega wa Bibeli mọ aya, to n pariwo ‘Jesu, Jesu’ lẹyin to gbọ idajọ iku tile-ejọ giga to wa niluu Akurẹ da fun un lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
Ọkunrin to sẹsẹ le logun ọdun ọhun ni wọn fẹsun kan pe o ṣeku pa ọkọ ẹgbọn rẹ, Olumuyiwa Adelọba, ni Ifira Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, lọjọ kọkandinlogun, osu kẹfa, ọdun 2018.
ALAROYE gbọ pe igba gbogbo ni ija ajaku akata maa n waye laarin Adelọba ati iyawo rẹ to jẹ ẹgbọn Adeọla, ṣugbọn eyi ti wọn ja lọjọ ta a n sọrọ rẹ yii lo sọ obinrin naa di ero ileewosan alabọọde kan to wa niluu ifira.
Ohun to bi awọn ẹbi obinrin naa ninu ree ti wọn fi lọọ ka ọkunrin yii mọle lati gbẹsan eeyan wọn to lu lalubami lara rẹ, asiko ti wọn n fa ọrọ ọhun mọ ara wọn lọwọ ni wọn ni Adeọla fa apola igi kan yọ, to si la a mọ ana rẹ lori nibi tawọn eeyan ti n la wọn nija, ti ọkunrin naa si gbabẹ ku.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Samuel Bọla ni ki wọn lọọ yẹgi fun olujẹjọ ọhun niwọn igba tawọn ẹri ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ laarin ọdun meji ti wọn fi gbọ ẹjọ yii ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ lo jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.