Ile-ẹjọ ni ki wọn yọ Adele-ọba Irele nipo bii ẹni yọ jiga

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Okitipupa, ti paṣẹ pe ki wọn yọ Ọmọọba Ọlanrewaju Ayerọmọra gẹgẹ bii adele-ọba ilu Ode-Irele lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti wa lori aleefa.

Lati ọdun 1993 ti Olofun tilu Irele to jẹ kẹyin, Ọba Ọlanrewaju Lẹbi, ti waja ni ọkan-o-jọkan wahala ti n su yọ lori ọrọ idile to lẹtọọ lati du oye ọba ilu ọhun. Ede-aiyede yii lo si ṣokunfa bi ipo ọba ilu ọhun ṣe ṣofo fun bii ọdun mọkandinlọgbọn gbako, ki ile-ẹjọ too ba wọn yanju rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Awọn eeyan idile Ọba Ọpẹtusin ni wọn lọọ pẹjọ ta ko idile kan ti wọn n pe ni Oyenusi, ti wọn si n bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ ka wọn lọwọ ko lati kopa ninu igbesẹ yiyan ọmọ-oye tuntun, eyi tawọn afọbajẹ fẹẹ bẹrẹ lọdun naa lọhun-un.

Idile ọba Ọpẹtusin nipasẹ agbẹjọro wọn, Amofin Bọde Famakin, ni ko sidii to fi yẹ kawọn eeyan idile Oyenusi ba awọn du oye naa, nitori pe wọn ko si ninu ojulowo awọn idile to n jọba ilu Irele.

Bakan naa ni wọn tun bẹ kootu ọhun lati rọ Adele-ọba to wa lori apere lọwọ loye, niwọn igba ti idile awọn ti fẹnu ko yan Ọmọọba Bamidele Ekunsanmi gẹgẹ bii ọmọ-oye tuntun.

Ki i ṣe idile Oyenusi nikan ni wọn pe lẹjọ, awọn mi-in to tun jẹ olujẹjọ ninu igbẹjọ ọhun ni Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, olubadamọran fun gomina lori ọrọ oye jijẹ, akọwe ijọba ipinlẹ Irele ati aṣoju idile Ọba Ọjọmọ, Oloye Claudius Lẹbi.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Tọpẹ Adedipẹ kọkọ paṣẹ fun ijọba ipinlẹ Ondo lati buwọ lu iyansipo Ọmọọba Bamidele Ẹkunsanmi gẹgẹ bii Olofun tuntun tilu Irele, kijọba si tun bẹrẹ igbesẹ lori bi wọn yoo se fun un ni ọpa asẹ lain ṣẹṣẹ tun maa fi akoko falẹ mọ.

Ile-ẹjọ ọhun tun paṣẹ fun Ọmọọba Ọlanrewaju Ayerọmọra lati jawọ ninu pipe ara rẹ ni Adele-ọba ilu Irele lati ọjọ naa lọ.

Leave a Reply