Ọwọ ọlọpaa tẹ ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun lasiko to fẹẹ lọ kọ lu awọn kan n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

 L’Ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ọwọ ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, tẹ ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Monday Ojoagbu, ni ile itaja igbalode kan lagbegbe Unity, niluu Ilọrin, pẹlu ibọn meji lasiko ti wọn fẹ lọọ ṣe akọlu si awọn kan.

Tẹ o ba gbagbe, lati bii oṣu meloo kan sẹyin ni ibẹru-bojo ti gbilẹ lawọn agbegbe kan niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, latari bi awọn ọmọ ẹgbẹ kunkun ṣe n rẹ ara wọn danu bii ila, ti wọn si n da awọn adugbo laamu. Lasiko ti wọn n gbaradi lati lọọ ṣe akọlu ọtun miiran ni ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ.

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE, lọwọ lo ti sọ pe ni ile itaja igbalode kan to wa ni agbegbe Unity, niluu Ilọrin, lọwọ ti tẹ ẹ, ti awọn ẹgbẹ rẹ si sa lọ. O tẹsiwaju pe ọwọ ọlọpaa ko ba tẹ awọn yooku rẹ, ṣugbọn wọn fi awọn onibaara to wa ninu ọja naa boju, wọn ko si fẹ ki nnkan bajẹ ninu ọja ọhun, eyi lo fun wọn laaye lati ribi sa lọ, ti iwadii si n lọ lọwọ lori bi wọn yoo ṣe ri awọn to sa lọ mu, ti wọn yoo si fi imu kata ofin.

Ibọn ibilẹ kekere kan ati ibọn katiriiji meji ni wọn ri gba lọwọ rẹ.

Leave a Reply