Adajọ paṣẹ kijọba Eko da iweerinna olukọ fasiti OOU ti wọn gbẹsẹ le pada fun un

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi wọn ṣe gba iwe irinna olukọ fasiti kan, Ọmọwe Adeṣọla Adeleke, lọna aibofin-mu, ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko, to wa laduugbo Ikẹja, ti paṣẹ fun gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati ijọba rẹ lati da iweerinna ọhun pada fobinrin naa.

Ọmọwe Adeleke, olukọ ni Fasiti Olabisi Onabanjọ (OOU), nipinlẹ Ogun, to tun jẹ ọmọbinrin Ọjọgbọn Duro Adeleke, iyẹn olori ẹka imọ Ẹda-Ede atawọn ede ilẹ Adulawọ (Linguistics and African Languages) ana ni Fasiti Ibadan (UI), nijọba ipinlẹ Eko da duro nigba to n bọ lati orilede South Africa, ti wọn si gba iweerinna ọwọ ẹ silẹ.

Ki i ṣe pe obinrin onimọ ijinlẹ nipa kẹ́míkà yii daran, bẹẹ ni ko rufin ijọba, kokoro arun Korona ni wọn sọ pe awọn ba ninu ẹjẹ rẹ lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe fun un nigba to de sorileede yii lati ilẹ South Africa.

Ohun ti wọn tori ẹ da iya naa duro fodidi ọsẹ meji ree, ti wọn si tun gba iweerinna oun atọmọ ẹ to n jẹ Adewumi Tiaramiyinoluwa Jean silẹ, ki wọn ma baa le kuro lorileede yii lọ sibikibi.

Ṣugbọn Ọmọwe Adeleke sọ pe ko si kokoro arun Korona kankan ninu ẹjẹ oun nitori ko too di pe oun kuro ni South Africa loun ti ṣayẹwo kan, ti abajade ayẹwo ọhun si fidí ẹ mulẹ pe ṣaka laara oun da.

Eyi lo mu ọmọ Ọjọgbọn yii yari, to si pe ijọba ipinlẹ Eko lẹjọ, o ni wọn purọ mọ oun, wọn tun dẹyẹ si oun lori arun ti oun ko ni, wọn si ṣe bẹẹ gbegi dina ominira oun.

Iyẹn lagbẹjọro rẹ, Amofin (Ọmọwe) Olutayọ Oyewale, ṣe sọ ni kootu ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pe ijọba ti tẹ ẹtọ onibaara oun loju. O waa rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ pe ki wọn da iweerinna awọn onibara oun pada fun wọn kiakia.

Nigba to n royin ohun ti wọn foju ẹ ri lori ọrọ naa, obinrin olupẹjọ yii ti ṣalaye pe “ileeetura kan ti wọn n pe ni Reginal Michael, n’Ikẹja l’Ekoo loun ti ṣeto pe oun maa de si lorileede yii pẹlu owo to n lọ bii ilaji miliọnu kan Naira (N481,890.00), ṣugbọn niṣe nijọba ipinlẹ Eko da eto naa ru, ti wọn si lọọ fi oun siileetura kan to dọti, to si kun fun kikida ẹfọn.

“Ko wu mi lati lọ sileetura yẹn rara, awọn eleto aabo ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ni wọn fi tipatipa mu mi lọ sibẹ.

“Mo ti ṣayẹwo kokoro arun Korona ni South Africa, eyi to fi han pe ko si kokoro arun Korona lara mi. Mo fi abajade ayẹwo yẹn han wọn, ṣugbọn wọn ni ki n tun lọọ tun omi-in ṣe l’Oluyọle, n’Ibadan. Ninu esi ayẹwo yẹn ni wọn ti sọ pe kokoro arun Korona wa ninu ẹjẹ mi.

Ṣugbọn nigba ti mo wo esi ayẹwo yii, wọn ti mu ayipada ba orukọ mi, ki i ṣe adirẹsi mi lo wa nibẹ. Ju gbogbo ẹ lọ, oju ọkunrin lo wa ninu fọto to wa ninu abajade ayẹwo yẹn, ki i ṣe temi rara.”

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro olupẹjọ atawọn  agbẹjọro ijọba, Adajọ ile-ẹjọ giga naa, Onidaajọ L.A.F Oluyẹmi, ni ki wọn da awọn iweerinna Ọmọwe  Adeleke ati tọmọ ẹ, Adewumi, pada fun wọn nipasẹ akọwe ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko laarin ọjọ meje si asiko tile-ẹjọ paṣẹ naa.

O waa sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni ọdun 2022.

Leave a Reply