Ile-ẹjọ sọ awọn ọmọ orileede India meji to n ji epo rọbi satimọle

Faith Adebọla, Eko

Afaimọ kawọn ọmọ ilẹ India meji yii, Akash Kumar ati Vishal Guleria ma rẹwọn he ti ajere ẹsun iwa ole jija ti wọn fi kan wọn ba ṣi mọ wọn lori.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, lo wọ wọn lọ sile-ẹjọ giga apapọ kan to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ka awọn afurasi ọdaran naa mọ ibi ti wọn ti n ṣe fayawọ epo rọbi ilẹ wa gba ori okun kọja. Nnkan bii marundinlaaadọta tọọnu oṣuwọn metric epo rọbi wa ni wọn ka mọ wọn lọwọ lai gbawe aṣẹ.

Agbẹjọro fun EFCC to jẹ olupẹjọ, Ọgbeni Usman Buhari, sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn ẹṣọ ologun ori omi ilẹ wa, Nigerian Navy, ka awọn afurasi naa mọbi ti wọn ti n fi ọkọ oju-omi nla kan ti wọn pe ni M.V. Bount ko epo rọbi ọhun atawọn ohun alumọọni ilẹ wa mi-in sa lọ.

O ni pẹlu iwadii tawọn agbofinro ṣe, awọn afurasi naa ko niwee aṣẹ kankan, wọn ko si gba ọna to bofin mu, niṣe ni wọn n ṣe fayawọ awọn ẹru naa, ti wọn si n pa ọrọ-aje wa lara.

Buhari ni iwa ti wọn hu naa ta ko isọri kẹta, abala kin-in-ni, iwe ofin oriṣiiriṣii aṣemaṣe ilẹ wa (Miscellaneous Offenses) ti ọdun 2004.

Amofin naa waa rọ ile-ẹjọ pe ki wọn da ọjọ pato ti igbẹjọ maa bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, ati lati ma ṣe gba beeli awọn afurasi mejeeji tori ajoji ni wọn, wọn le gba ọna ẹburu sa lọ.

Ile-ẹjọ beere lọwọ awọn afurasi ọdaran naa boya wọn jẹbi, ṣugbọn wọn ni awọn ko jẹbi.

Lẹyin eyi ni Adajọ Rilwan Aikawa gba ẹbẹ mejeeji ti olupẹjọ beere fun wọle. O ni ki igbẹjọ ẹni akọkọ, Ọgbẹni Kumar, bẹrẹ lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, nigba ti igbẹjọ ekeji rẹ yoo bẹrẹ lọjọ keji, iyẹn ọjọ kẹrinla.

Lafikun, adajọ paṣẹ pe ki wọn ṣi lọọ fi wọn pamọ sahaamọ EFCC, ki wọn waa taari wọn si ọgba ẹwọn Ikoyi to ba ya, titi di ọjọ igbẹjọ to n bọ.

 

Leave a Reply