Ile-ẹjọ sọ eeyan mẹwaa ṣewọn l’Ekiti, idọti ni wọn da soju titi

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majisreeti alagbeeka to wa niluu Ado-Ekiti ti ṣedajọ ẹwọn ọṣu meji fawọn mẹwaa kan tọwọ tẹ pe wọn tapa si ofin imọtoto lagbegbe Ajilosun ati NTA, niluu naa.

Alaba Kọlade, Kẹmi Adetimi, Iyabọ Ojo, Victoria Ajayi, Ọmọlara Ọlaoye, Risikat Sunday, Wuraọla Ilọri, Aarinọla Ọlayẹmi, Suleiman Hamed ati Rotimi Tadeolu ni ikọ kan nileeṣẹ eto ayika wọ lọ si kootu ọhun leyin tọwọ tẹ wọn.

Abilekọ Bọlaji Ogunsan fẹsun kan awọn eeyan naa pe wọn huwa to ta ko ofin ilera agbegbe ati kolẹ-kodọti tijọba Ekiti ṣagbekalẹ lọdun yii.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Majisreeti Timothy Abe fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn eeyan naa huwa ọhun, o si di dandan ki wọn lọọ ṣẹwọn oṣu meji tabi sanwo itanran ẹgbẹrun marun-un ẹnikọọkan.

Ọkan ninu awọn arufin naa ti ko lowo lati san ni kootu ọhun foju aanu wo, ijiya rẹ si ni lati ṣiṣẹ kolẹ-kodọti lawọn agbegbe kan.

Kọmiṣanna fọrọ ayika, Abilekọ Iyabọ Fakunle-Okieimen, waa koro oju si bawọn eeyan ko ṣe bikita nipa ọrọ imọtoto, bẹẹ lo kilọ fawọn arufin lati so ewe agbejẹ mọwọ nitori ẹni tọwọ ba tẹ yoo jiya labẹ ofin.

 

Leave a Reply