Ile-ẹjọ ti paṣẹ ki wọn ju Ahmed Idris, oluṣiro owo agba tẹlẹ, satimọle

Monisọla Saka

Ọjọ Ẹti, Furaidee, opoin ọsẹ yii ni Onidaajọ Adeyẹmi Ajayi paṣẹ pe ki wọn sọ oluṣiro owo agba ilẹ wa tẹlẹ, Ahmed Idris, satimọle, ninu ọgba ẹwọn Kujen latari ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.

Oun atawọn olujẹjọ mẹta mi-in ti wọn jọ fẹsun kan nile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ mi-in yoo fi waye lori ọrọ wọn.

Ẹsun mẹrinla ọtọọtọ ni wọn fi kan awọn eeyan naa niwaju adajọ ile-ẹjọ giga ilu Abuja. Wọn ni wọn ṣafọwọra, bẹẹ ni wọn tun ṣe owo to din diẹ ni aadọfa biliọnu Naira(109.4 billion) mọkumọku.

Ọgbẹni Idris atawọn ẹmewa ẹ rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa (EFCC), fi kan awọn.

Chris Uche to jẹ agbẹjọro Idris bẹ ile-ẹjọ lati gba onibaara rẹ laaye ominira, ko si le maa rin yan fanda kiri gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe ti gba a laaye.

O ṣalaye fun kootu pe iwe irinna olujẹjọ ṣi wa lakata ajọ EFCC, fun idi eyi, ki wọn gba awọn laaye lati pada wa lọjọ Aje, Mọnde, lati gba beeli ẹ.

Ni ti Rotimi Jacobs, to jẹ agbẹjọro fun ajọ EFCC, niṣe lo fesi pe wọn o lẹtọọ lati gba beeli rẹ mọ nigba tọrọ ti dele-ẹjọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Onidaajọ Adeyẹmi paṣẹ pe ki wọn ko awọn olujẹjọ lọ si atimọle ọgba ẹwọn Kuje, o si sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje ọdun yii, fun igbẹjọ lori beeli ti wọn fẹẹ gba fun un.

Awọn olujẹjọ to ku ni: Oluṣẹgun Akindele, Mohammed Usman ati ileeṣẹ Gezawa Commodity Market and Exchange Limited.

Tẹ o ba gbagbe, oluṣiro owo agba fun ilẹ Naijiria yii ni ajọ EFCC mu lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ta a wa yii lori ẹsun arọndarọnda owo to to ọgọrin biliọnu Naira ti wọn ka si i lọrun.

Idris ni wọn fi panpẹ ofin gbe lẹyin tawọn ajọ yii ranṣẹ pe e, to kọ, ti ko si yọju lori ọrọ owo to ṣe mọkumọku.

Lẹyin eyi ni minisita fun eto iṣuna, inawo ati eto ilu, Zainab Ahmed, sọ pe ko lọọ rọọkun nile lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o n ko owo ilu sinu awọn apo owo ara rẹ nipasẹ lilo apo ikowosi banki awọn mọlẹbi ati eeyan rẹ nipa fifi ra awọn ile ati ilẹ si Kano ati Abuja.

Ni bayii, adajọ ti ni koun atawọn olujẹjọ to ku wa latimọle titi di ọjọ igbẹjọ mi-in.

Leave a Reply