Ile-ẹjọ yẹ aga nidii aṣofin APC ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nile-ẹjọ to n gbọ ẹhonu ibo, to fikalẹ siluu Ilọrin kede oludije ẹgbẹ PDP, Ọnarebu Salihu Muhammad Yahaya, gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo sileegbimọ aṣofin Kwara lati ṣoju Patigi, eyi to waye lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2020.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun yii, ni ajọ eleto idibo kede oludije APC, Adam Ahmed Rufai, bii ẹni to jawe olubori atundi ibo naa, ṣugbọn Yahaya to ṣoju PDP tako o, o si gba ile-ẹjọ lọ.

Dokita Abdulazeez Iṣhọla Musbau, ti Fasiti Ilọrin kede nigba naa pe Rufai ni ibo to le lẹgbẹrun mẹwaa lati fagba han awọn ẹgbẹ rẹ marun-un yooku ti wọn jọ dupo naa.

Rufai lo dije lati rọpo ẹgbọn rẹ, Ọnarebu Saidu Ahmed Rufai, to n ṣoju Patigi tẹlẹ, ẹni to doloogbe loṣu kejila, ọdun 2019,  lẹyin aisan to ba a finra.

Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹfa to kopa ninu atundi ibo naa ni; AAC, ADC, APC, APM, NNPP ati PDP tajọ INEC kede pe o ṣe ipo keji.

Ẹwẹ, Alaga ẹgbẹ PDP, Ọnarebu Kọla Ṣhittu, ti gboṣuba fun ile-ẹjọ lori idajọ naa. O ni yoo mu ki araalu tubọ nigbagbọ ninu eto idajọ.

O waa ke si ile aṣofin Kwara lati bura wọle fun Ọnarebu Raheem Agboọla, ẹni tile-ẹjọ ti kede ṣaaju pe o jawe olubori gẹgẹ bii oludije to n ṣoju ẹkun Ilọrin South, nileegbimọ aṣofin.

 

Leave a Reply