Ilẹ Hausa ni wọn ti n jẹ anfaani ọpọ nnkan amuṣọrọ to jẹ ti ilẹ Yoruba -Ọọni

Adebiyi Adefunkẹ, Abẹokuta

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ti sọ  pe bi ko ba si atunto  lori bi nnkan ṣe n lọ ni Naijiria yii, laarin ọdun mẹta si asiko yii, a jẹ pe ọjọ iwaju orilẹ-ede naa lewu gidi, nitori ko si ireti kankan fun ilẹ yii niyẹn.

Ikẹja ni Aarẹ ti sọrọ yii, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹrin yii, lasiko ti wọn n fi iwe kan ti wọn pe orukọ ẹ ni  ‘Roundtable  Discussion on Economy and Restructuring in Nigeria, lọlẹ. Nibẹ ni Aarẹ ti sọ pe ọpọlọpọ ọmọ Yoruba lo ti ṣetan lati pinnu ohun ti wọn n fẹ, bẹẹ si ni oriṣiiriṣii atunto lo wa, afi ki wọn mọ iru atunto ti wọn n fẹ. Ati pe eekan pataki kan wa to le mu atunto naa ya, ṣugbọn ko jọ pe alagbara naa ti i ṣetan rara, ohun ti ọpọlọpọ awọn agbaagba Yoruba n beere fun niyẹn.

O tẹsiwaju pe bi atunto yoo ba waye ni Naijiria, a gbọdọ  mu lo ninu awọn koko ọdun 1960 si 1963, eyi to faaye silẹ fun iṣejọba ẹlẹkunjẹkun, to si tun faaye silẹ fun ẹkun mẹfẹẹfa lati ni idagbasoke bi agbara wọn ba ṣe pọ si. ‘‘Ohun ti emi n fẹ ni ipinnu ọkan mi, ka gbaradi fun idunaa-dura’’ Bẹẹ ni Aarẹ wi.

Aarẹ sọ pe loootọ loun fara mọ ero ọpọ eeyan ti wọn n sọ pe Naijiria ti kuro nipele bibeere fun atunto, ṣugbọn nigba ti ohun ti yoo jẹ ki ipinnu ẹni kọọkan waye ko ti i si nkọ.

Bakan naa ni Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti Alara Oodaye Ifẹ, Ọba Ṣẹgun Layade, ṣoju fun, ṣalaye pe ilẹ Hausa ni wọn ti n jẹ anfaani ọpọ nnkan amuṣọrọ to jẹ ti ilẹ Yoruba. Bakan naa lo ni ki wọn da ẹkọ nipa itan (History) ti wọn yọ kuro ninu iṣẹ tawọn akẹkọọ n kọ nileewe, pada.

Oloye Bọde George ti Ọmọwe Charles Akitoye, ṣoju fun naa sọ pe bi Naijiria  ṣe wa yii labawọn, bẹẹ si ni ilẹ Hausa ni gbogbo ọrọ ajẹ ilẹ yii dojukọ.

Leave a Reply