Ilẹ mọ ba eleyii, ayederu owo Naira lo fẹẹ na fun oni POS

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ni Omidan Linda Ihebinike wa bayii to ti n gbatẹgun. Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe mu un pe o fẹẹ na ayederu Naira fun oni POS kan niluu Eko laipẹ yii wa.

ALAROYE gbọ pe laaarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni Linda ko ẹgbẹrun lọna aadọrun-un Naira to jẹ kikida ẹgbẹrun Naira lọ sọdọ oni POS kan  laduugbo rẹ, o ni ko b’oun sẹndi rẹ si akanti ẹnikan. Ṣugbọn nitori pe oni POS ọhun ko sun asunpiye rara, paapaa ju lọ bi Linda ṣe n ṣe waduwadu lọjọ naa lo mu ki iyẹn fura si i, to si yẹ awọn owo naa wo daa. Nigba naa lo ṣakiyesi pe ayederu owo ni Linda ko waa ba oun lọjọ naa. Loju-ẹsẹ lo ti figbe bọ’nu tawọn eeyan si tete dide iranlọwọ si i. Awọn kan tiẹ ti fẹẹ lu Linda bajẹ fohun to ṣe, ṣugbọn nitori pe obinrin ni, wọn ko jẹ ki wọn fọwọ ba a pupọ ti wọn fi fa a le awọn ọlọpaa agbegbe naa lọwọ pe ki wọn ba a ṣẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ọdọ awọn ni Linda wa bayii to n ran awọn lọwọ ninu iwadii tawọn n ṣe nipa ẹsun ọdaran tawọn araalu fi kan an.

Alukoro ni awọn maa ṣewadi daadaa lati mọ ibi tabi ẹni to ko aduru ayederu owo naa fun un, ati pe laipẹ yii lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ, ko le jiya ẹṣẹ rẹ.

 

Leave a Reply