Ọrọ di ilu gangan n’Ibadan: Wọn n sunkun nile Ọba Balogun, wọn n yọ nile Ọba Ọlakulẹhin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nibi tẹlẹkun ti n sunkun lalayọ ti n yọ, bi awọn leekan leekan ilu ṣe n lọ si adugbo Alarere, n’Ibadan, nile Ọba Lekan Balogun, Olubadan ilẹ Ibadan to waja lati ṣedaro pẹlu awọn ẹbi ẹ, bẹẹ lero rẹpẹtẹ n ya lọ sile agba ijoye ọba naa, Ọba Akinloye Owolabi Ọlakulẹhin, lati ki i kuu oriire, nitori oun nipo ọba kan wayi gẹgẹ bi wọn ṣe ṣeto ọba jijẹ ilu naa.

O fẹẹ jẹ pe ile Ọlakulẹhin ti i ṣe Balogun ilẹ Ibadan lọwọlọwọ lawọn ero rẹpẹtẹ n ya lọ ju lọ ni gbogbo ilẹ Ibadan bayii, nitori bi wọn ṣe n lọ si agboole wọn to n jẹ Ile Ọlakulẹhin, laduugbo Ita Baalẹ, lati ki awọn mọlebi ẹ kuu oriire, loun funra rẹ ko sinmi igbalejo awọn eeyan nile ẹ to wa laduugbo Alalubọsa, lagbegbe Iyaganku, n’Ibadan.

Ko too di pe wọn sinku Ọba Balogun lawọn eeyan ti n ya lọ si awọn ile mejeeji yii lati ki ẹni ti ipo Olubadan sun kan yii kuu imurasilẹ oriire to n kanlẹkun ile ẹ dẹ̀dẹ̀ yii.

Tẹ o ba gbagbe, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, l’Ọba Balogun waja sileewosan ijọba apapọ, University College Hospital, to wa ni’Ibadan.

Lọjọ keji, iyẹn, ọjọ Jimọ, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ti wọn sinku ẹ si agboole wọn ni Aliwo, n’Ibadan, lawọn onilu ọba Ibadan ti kuro ni Aliwo, ti wọn si gba ọdọ Ọlakulẹhin lọ, nile ẹ to wa l’Alalubọsa, n’Ibadan.

Igbesẹ ti awọn onilu gbe yii lo tọka si pe bi ọla ṣe ṣi kuro laafin ọba to waja, lọla ṣi lọ sile ẹni ti gbogbo aye n reti gẹgẹ bii ọba tuntun.

Bi awọn mọlẹbi Ọlakulẹhin ko ṣe le pa idunnu wọn mọra, ti wọn n kọrin ayọ pe :

“oye naa koo lee waa

O di koro”,

bẹẹ lawọn onilu to ti sọ ibẹ di ibi iṣẹ tuntun bayii naa n kanlu si wọn nibadi, ti wọn si n filu ki awọn alejo gbogbo kaabọ si ile ọla tuntun.

Bi ohun gbogbo ba lọ bo ṣe yẹ, ti Ọlakulẹhin gori apere awọn baba nla ẹ, oun ni yoo jẹ ẹni akọkọ ti yoo de ade Olubadan ninu iran wọn.

Loootọ, Oyeṣile Olugbode, to jẹ baba nla fun un naa ti ṣakoso ilẹ Ibadan ri laarin ọdun 1851 si 1864, ṣugbọn Baalẹ ni baba naa jẹ, nitori baalẹ lasan ni wọn n jẹ n’Ibadan nigba naa, wọn o ti i maa jọba ta a mọ si Olubadan lonii. Baalẹ Olugbode si ni Baalẹ Ibadan keje.

Awọn agbaagba ijoye Ibadan yooku ta a tun mọ si igbimọ Olubadan paapaa wa lara awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan ti wọn ti lọọ ki baba ti ipo ọba kan yii sile.

Ninu awọn igbimọ Olubadan ọhun ni: gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan,  to tun jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan lọwọlọwọ; Sẹnetọ Raṣidi Adewọlu Ladọja, Ọba Amidu Ajibade ti i ṣe Ẹkẹrin Olubadan; Ọba Adebayọ Akande (Ẹkarun-un Olubadan); Ọba Abiọdun Kọla-Daisi ati bẹẹ, bẹẹ lọ, titi dori awọn Mọgaji ilu Ibadan.

 

Leave a Reply