Ọkunrin yii ji ara ẹ gbe pamọ, eyi nidi to loun fi ṣe bẹẹ

Monisọla Saka

Ọwọ awọn agbofinro Abuja ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) kan, Pascal Akuh, to parọ pe wọn ji oun gbe lati fi dan iyawo afẹsọna rẹ wo.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni CP Ben Igweh, ti i ṣe kọmiṣanna ọlọpaa ilu Abuja, sọrọ naa lasiko ti wọn n foju awọn afurasi ọdaran hande. O ni Pascal ni oun fẹẹ mọ bi afẹsọna oun ṣe nifẹẹ oun to lo jẹ k’oun jira oun gbe pamọ.

Kọmiṣanna ni, “Ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ọkunrin kan to n jẹ Akuh Chinemezeh wa si agọ ọlọpaa Apo, lati fi to awọn agbofinro leti pe aburo oun ọkunrin, Pascal Akuh, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), pe oun lori aago pe awọn ọlọpaa mu oun, wọn si ti gbe oun lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran, State Criminal Investigation Department (SCID).

“Nitori ọrọ yii, ni kiakia ni awọn agbofinro atawọn mọlẹbi afurasi ti gba SCID lọ, latibẹ ni wọn tun ti lọ si ẹka IRT ati FCID, ṣugbọn ti wọn ko ri i lọna mẹtẹẹta yii. Pẹlu iranlọwọ ohun eelo imọ ẹrọ kan ti wọn fi maa n tọpasẹ nnkan (Tracker), ni wọn fi tọpinpin ọkọ afurasi lọ si agbegbe Wumba, Apo, niluu Abuja.

“Loju-ẹsẹ ti wọn ti fi ọrọ yii to wọn leti ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ teṣan Apo ti gba ibẹ lọ, wọn gbọn agbegbe ibẹ yẹbẹyẹbẹ titi ti wọn fi ka afurasi ọhun mọ ileetura kan lagbegbe Lokogoma, lọwọ alẹ, ti wọn si fi panpẹ ofin gbe e”.

Ọga ọlọpaa yii ṣalaye siwaju pe lasiko ti wọn n fọrọ wa Pascal lẹnu wo lo jẹwọ pe oun kan dibọn pe wọn ji oun gbe ni. Ati pe, nitori nnkan meji kọ, lati fi le dan iyawo afẹsọna oun wo boya o nifẹẹ oun daadaa ni.

 

Leave a Reply