Ọkẹ aimọye dukia jona deeru ninu iṣẹlẹ ijamba ina n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, inu adanu nla ni awọn to n gbe ile oniyara mẹfa kan l’Opopona Àdúràmígbà, lagbegbe Akérébíata, niluu Ilọrin wa bayii. Ina lo jo awọn yara ọhun gburugburu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ku fẹẹrẹfẹ niṣẹlẹ naa waye, kẹu-kẹu bii ibọn ni ina naa n dun, to si ṣe bẹẹ jo awọn dukia to wa ninu yara mẹfẹẹfa to wa ninu ile ọhun.

Gbogbo igbiyanju awọn araadugbo lati pa ina naa lo ja si pabo. Nitori wọn ko tete ri awọn panapana ke si lo mu ki ina ọhun bu gbamu si i titi to fi jo yara mẹfẹẹfa kanlẹ.

Arakunrin kan to n gbe lagbegbe naa ṣalaye fun akọroyin wa pe ni nnkan bii aago mọkanla ku ogun iṣẹju laaarọ ni ijamba ina naa bẹrẹ, ti gbogbo olugbe agbegbe ọhun si n gbiyanju agbara wọn lati pa a kawọn panapana too de.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ṣe ni awọn gba ipe pajawiri lati ọdọ ọkunrin kan, Ọgbẹni Abdulmumeen, to n gbe ni agbegbe naa, pe ina n ṣọṣẹ lọwọ ni Akérébíata, tawọn si sare gbe ọkọ lọ lati lọọ pana ọhun, bo tilẹ jẹ pe nnkan ti bajẹ jinna kawọn too gunlẹ sibi iṣẹlẹ naa.

O tẹsiwaju pe gbogbo yara to wa nibẹ lo jona gburugburu, ati pe ina ẹlẹntiriiki to ṣẹju lo ṣokunfa ijamba naa. O ni ni kete ti ajọ panapana gunlẹ sibẹ naa ni wọn ti kapa rẹ, ti wọn si pa a patapata, ko maa baa ran mọ awọn ṣọọbu miiran to sun mọ ọn.

Ọga ajọ yii ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa ki wọn maa wa loju ni alakan fi n ṣọri lọfiisi ati ninu ile, ki wọn si maa yago fun gbogbo ohun to le ṣokunfa ijamba ina layiika wọn.

Leave a Reply