Ẹfun abeedi! Ọmọ ti obinrin yii gba tọju gun un lọbẹ pa l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ileeṣẹ ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori iku abilekọ kan, Florence Adelayi, ẹni ti wọn ba oku rẹ nibi ti wọn gun un pa si ninu yara ile to n gbe ninu Ẹsiteeti Premier, to wa laduugbo Okunbadejọ, niluu Ọda, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

ALAROYE gbọ latẹnu awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn pe oku iya ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta ọhun ni wọn ṣawari ninu yara rẹ lẹyin ti oorun buruku to n jade lati inu ile to ku si ko jẹ kawọn ti wọn jọ n gbe adugbo sinmi.

Oṣiṣẹ ijọba ni Oloogbe ọhun, airọmọ bi i rẹ ni wọn lo ṣokunfa bo ṣe lọọ gba ọmọdebinrin ẹni ọdun mejila kan ti wọn porukọ rẹ ni Wumi tira, oun ati ọmọbinrin yii ni wọn si jọ n da gbe ile rẹ to n gbe niluu Ọda.

Inu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ni wọn ni arun ọpọlọ bẹrẹ si i yọ ọmọbinrin yii lẹnu, ti Abilekọ Adelayi si gbiyanju lati tọju rẹ titi, ṣugbọn ti ko si ayipada rara.

Gbogbo imọran tawọn eeyan si n gba a pe ko da ọmọ yii pada sọdọ awọn obi rẹ ko wọ ọ leti, ṣe lo tẹra mọ itọju rẹ, ti ko si si ibi ti ko gbe e de fun itọju.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta yii, lawọn araadugbo ri obinirn yii gbẹyin, ọpọ wọn ni wọn ri i ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lọsan-an ọjọ naa nigba to n bọ lati ibi iṣẹ, ṣugbọn ti ko ṣẹni to tun kofiri rẹ mọ latigba naa.

Ohun ti ko jẹ k’awọn eeyan tete fura pe nnkan buruku ti sẹlẹ si obinirn yii ni pe ita ni wọn ti geeti rẹ pa si, leyii to mu k’awọn ti wọn jọ wa laduugbo ro pe ṣe lo ti lọ si irinajo.

Awọn eṣinṣin ọdẹ dudu kan tawọn eeyan ṣakiyesi to n jade lati inu ọgba ile rẹ wa pẹlu abami oorun diẹdiẹ ti wọn n gbọ lo mu ki wọn pe awọn ẹbi obinrin yii sori aago lati fi ohun ti wọn ṣe akiyesi to wọn leti.

Kayeefi nla lo si jẹ fun wọn lẹyin ti wọn ja geeti wọle tan nigba ti wọn ba oku rẹ nibi ti wọn pa a si nilẹẹlẹ yara rẹ. Ẹyin ni wọn ti gun un lọbẹ, ti ẹni ọhun si tun fi ọbẹ naa si ẹgbẹ oku rẹ nibẹ.

Wọn sare lọọ fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa Àlà leti, awọn ni wọn si ṣeto bi wọn ti gbe oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa l’Akurẹ.

Ko ṣẹni to mọ bi ọmọbinrin yii ṣe rin latigba naa, ṣugbọn a gbọ pe ọwọ awọn agbofinro ti pada tẹ ẹ lagbegbe kan ti wọn n pe ni Pẹlẹbẹ, loju ọna Ọ̀dá si Akurẹ, ti wọn si ti mu un lọ si teṣan wọn lati fọrọ wa a lẹnu wo.

Leave a Reply