O ga o! Eyi lohun tawọn ajafẹtọọ ṣe fun’yawo Mohbad

Monisọla Saka

Wọn n pe ọrọ iku ọkunrin olorin taka-sufee ilẹ wa to ku loṣu Kẹsan-an, ọdun to kọja lọ nni, iyẹn Mohbad, lowe, ṣugbọn o ti n ni aro ninu bayii pẹlu bi wọn ṣe kọ lẹta sileeṣẹ awọn ilẹ okeere nilẹ Naijiria, lati ma ṣe jẹ ki iyawo rẹ jade kuro niluu.

Ọkunrin ajafẹtọọ-ọmọniyan kan, Akinọla Adelabu-Soul, lo tẹsẹ bọ ṣokoto pẹlu iyawo ti Mohbad fi saye, iyẹn Ọmọwunmi Alọba, ati ọmọ wọn, Liam, nigba to kọwe sawọn alaṣẹ lati dena irinajo to ba le gbe obinrin naa kuro ni Naijiria.

Ileeṣẹ ilẹ okeere mẹtala ọtọọtọ ti wọn wa lorilẹ-ede yii ni Adelabu kọ lẹta si lati maa ṣakiyesi, ki wọn si gbegi dina ati jade iyawo Mohbad, ati ọmọ ẹ kuro ni Naijiria.

O ni ijaya ati ibẹru iku ọkunrin naa ṣi wa lara awọn ololufẹ ati akẹgbẹ ẹ, ti ọpọlọpọ si n fura pe ejo iku rẹ lọwọ ninu.

Awọn orilẹ-ede bii Amẹrika, Brazil, France, Italy, Russia, UK, Switzerland, Germany, Cyprus, Greenland, Canada, Korea ati China, ti ileeṣẹ wọn wa nilẹ yii, ni wọn fi lẹta naa ṣọwọ si.

O ni ọkan pataki ninu igbesi aye oloogbe Mohbad ni Wumi iyawo ẹ jẹ, ati pe ọrọ to wa nilẹ lẹyin iku rẹ lagbara, o si ni lati yanju ki obinrin naa too le yẹra.

Adelabu to rọ awọn ileeṣẹ yii lati maa kiyesara, ki wọn ma si ṣe gba a laaye lati rinrin-ajo titi ti iwadii yoo fi pari sọ ninu lẹta naa bayii pe, “Laipẹ yii, ileeṣẹ orin ilẹ Naijiria padanu ọkunrin olorin to ni ẹbun pataki nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad, pẹlu iku aitọjọ.

Iku rẹ ti ko awọn ololufẹ atawọn akẹgbẹ rẹ sinu ipaya, bẹẹ ni oniruuru nnkan lawọn eeyan fẹẹ mọ nipa ohun to ṣokunfa iku rẹ.

“Ọmọwunmi, obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti i ṣe iyawo oloogbe jẹ ọkan pataki lara igbesi aye ẹ nigba to wa laye. Tọkọ-tiyawo ni wọn, Ọlọrun si fi ọmọ kan, to n jẹ Liam ta wọn lọrẹ. Gẹgẹ bi iwadii ṣe n lọ, o ti n foju han pe o ṣee ṣe ki nọọsi kan lọwọ ninu ohun to fa iku rẹ. Awọn ọlọpaa ti hu oku rẹ fun ayẹwo, gbogbo ọrọ to wa nilẹ naa si jẹ eyi to gbẹgẹ.

“Nitori eyi, mo n rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ yin ni Pataki, lati maa ṣe oju lalakan fi n ṣọri lori ọrọ ẹ, ki wọn si gbegi dina Wumi ati ọmọ ẹ lati kuro ni Naijiria titi ti iwadii yoo fi pari.

“Igbagbọ mi ni pe ileeṣẹ yin yoo gbe igbesẹ kiakia lori ọrọ yii. Awọn ọmọ Naijiria n fẹ idajọ ododo, a si gbagbọ pe ifọwọsowọpọ yin yoo ko ipa pataki lojuna ati mu ko wa si imuṣẹ”.

Lai duro nibẹ, Adelabu tun fi ẹda lẹta yii ranṣẹ si ileeṣẹ to n ri si wiwọle ati jijade lorilẹ-ede yii, Nigerian Immigration Service (NIS), ati olu ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa.

O rọ wọn lati maa ṣọ Wumi lori ọrọ irinajo, ki wọn ma si ṣe jẹ ko kuro lorilẹ-ede yii, bẹẹ lo bẹ awọn ọlọpaa naa lati kun awọn lọwọ ninu iṣẹ yii, lati ri i daju pe ko rọna jade kuro ni Naijiria.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ni Mohbad dagbere faye lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Nitori awuyewuye to su yọ lori iku to pa a yii ni awọn ọlọpaa fi bẹrẹ iwadii, ti wọn hu oku ẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, kan naa.

Leave a Reply