Ọwọ sifu difẹnsi tẹ awọn afurasi ajinigbe marun-un l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ninu igbo ọba kan lagbegbe Eti-Ọsẹ, nijọba ibilẹ Ọwọ, lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afurasi ajinigbe marun-un, lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Alukoro ajọ ọhun, Aidamenbor Daniel sọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ALAROYE pe mẹrin ninu awọn tọwọ tẹ ọhun, iyẹn, Dahiru Abdullahi, ẹni ọdun marundinlọgbọn, lati ipinlẹ Kogi, Isiaku Jubril, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, Nura Idris, ẹni ọgbọn ọdun ati Muhammed Suleiman, to jẹ aadọta ọdun ni iwadii fidi rẹ mulẹ pe ogbologboo ajinigbe ni wọn, nigba ti ẹni karun-un wọn, Uyobon Jim, ẹni ọgbọn ọdun, jẹ agbodegba fun wọn.

O ni laarin aago mẹfa aabọ aarọ si mẹfa aabọ alẹ lọwọ tẹ wọn lọjọ naa pẹlu iranlọwọ awọn fijilante. Lasiko naa lo ni awọn ẹsọ alaabo yii atawọn janduku ọhun doju ibọn kọra wọn, ṣugbọn ọwọ awọn agbefọba yii dun wọn, ti awọn si fi pampẹ ofin gbe marun-un ninu wọn.

Alukoro ni Dahiru lọwọ kọkọ tẹ lẹyin toun atawọn ọmọ igbimọ rẹ ji awọn eeyan kan gbe, ti wọn si gba miliọnu mẹfa ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (6.2m) lọwọ wọn. Lẹyin eyi lo ni ọwọ tun tẹ Jim, to jẹ agbodegba wọn ninu oko igbo rẹ.

Inu igbo ọba to wa ni Ìpelè, abule Abuṣọrọ, n’ijọba ibilẹ Ọwọ, lo ni ọwọ ti tẹ Jibril, Nura ati Muhammed, lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii kan naa, nibi ti wọn ti n gbiyanju ati ji ẹnikan to kọ lati darukọ rẹ gbe.

Lara awọn ẹru ofin to ni awọn ba ni awọn ba nikaawọ awọn afurasi ọhun ni: ibọn agbelẹrọ meji, ada mẹta, oriṣii foonu mẹrin, nọmba idanimọ NIN kan, kaadi idibo mẹrin, kaadi ipọwo (ATM) kan, ọkada TVS kan, ọta ibọn loriṣiiriṣii ati ẹwu awọn agunbanirọ kan.

Aidamenbor ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lori bi awọn afurasi ọhun yoo ṣe foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply