Ọwọ tẹ ayederu Dokita l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ awọn Dokita lorilẹ-ede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, ti ṣe afihan ayederu Dokita kan, Ọgbẹni Ọlalekan Timothy Faṣipẹ. Ọkunrin yii ni wọn ṣe awari rẹ lẹyin ti aṣiri rẹ tu sọwọ awọn Dokita pe ayederu iwe-ẹri ti ko wa lati ọdọ ajọ awọn Dokita ni Naijiria, iyẹn, (Medical and Dental Council of Nigeria), lo n gbe kiri.

Afurasi ayederu Dokita yii jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ekiti, (Hospital Management Board) to tun jẹ oloye ninu ẹgbẹ awọn oniṣegun yii lo n pere ra rẹ ni ogbontarigi Dokita, ti ko si niwe-ẹri kan pato.

Ninu atẹjade kan lati ọdọ ẹgbẹ awọn Dokita ipinlẹ Ekiti, eleyii ti alaga wọn, Dokita Babatunde Rosiji ati Akọwe ẹgbẹ naa, Dokita Moses Dada, gbe jade ni wọn ti sọ pe ẹgbẹ naa ti n ṣe gbogbo ohun to wa ni ikapa wọn pẹlu ifọwọsọwọpọ ile-iṣẹ eto ilera ipinlẹ Ekiti, lati fopin si ayederu dokita laarin wọn.

Wọn ni, “Bi aṣiri Ọgbẹni Ọlalekan Timothy Faṣipẹ ṣe tu pe ayederu  Dokita ni ya gbogbo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ekiti lẹnu, ohun to mu kọrọ naa buru ni pe ọkan ninu awọn oloye ni afurasi yii ninu ẹgbẹ awọn dokita ipinlẹ Ekiti, ki aṣiri rẹ too tu.

“A tun ti ri iwe kan gba latọdọ awọn ẹgbẹ awọn dokita to n ṣe itọju ẹyin, (Medical and Dental Council of Nigeria (MDCN), pe orukọ Fasipẹ Ọlalekan Timothy ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ ajọ naa, ati pe orukọ naa ko si ninu iwe ti wọn kọ orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ awọn si.

“Ni kete ti a ti ri iwe yii gba ni ẹgbẹ wa ti ranṣẹ pe Faṣipẹ pe ko yee pe ara rẹ ni Dokita, ko si yago ninu pipe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ wa, nitori pe ko ni iwe-ẹri to le fi pe ara rẹ ni Dokita alabẹrẹ to daju. Lẹyin eyi la yọ orukọ rẹ kuro lara awọn ọmọ ẹgbẹ wa.

“Iṣẹ wa jẹ iṣẹ pataki, to si tun gbẹlẹgẹ pupọ laarin awujọ, nitori o ni i ṣe pẹlu ẹmi eeyan, idi niyi ti awa Dokita ṣe maa n ni eto ẹkọ tio peye, yala lati Oke-Okun tabi lorilẹ-ede yii.”

Awọn aṣaaju ninu ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo nipinlẹ Ekiti fi aidunnu wọn han lori iṣẹlẹ naa, wọn ṣalaye pe awọn ọlọpaa ati ileeṣẹ eto ìdájọ gbọdọ ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn foju ọdaran ti ọwọ te naa wina ofin. Baka naa naa ni wọn tun gbọdọ ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn fi kele ofin gbe iru awọn ti wọn n pe ara wọn ni ohun ti wọn ko jẹ yii.

Awọn ẹgbẹ oniṣegun oyinbo yii ni awọn ti fa ọdaran naa le awọn agbofinro lọwọ fun iwadii ati ijiya to yẹ.

Leave a Reply