Adajọ ju Wasiu sẹwọn gbere l’Ekoo, ohun to ṣe buru jai

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Rahman Oṣhodi, tile-ẹjọ kan to ri si lilo ọmọde ni ilokulo ati fifipa ba obinrin lo pọ, ‘Sexual Offences And Domestic Violence Court’ kan to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, ni wọn foju Ọgbẹni Rasheed Wasiu ba lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii. Ẹsun tijọba ipinlẹ Eko fi kan an ni pe o fipa ba ọmọọdun mọkanla to jẹ ọmọ araale rẹ, lagbegbe Apapa, niluu Eko sun.

ALAROYE gbọ pe loṣu Kẹta, ọdun 2018, lasiko tọmọ ọhun ṣi wa lọmọ ọdun mọkanla pere ni Wasiu fipa ba a sun ninu ile igbọnsẹ ti wọn n lo to wa lẹyinkunle ile ọhun.

Ile elero to pọ ni awọn obi ọmọ ọhun ati Wasiu jọ n gbe, ṣugbọn loṣu Kẹta, ọdun 2018 tọmọ ọhun fẹ lọọ ṣegbọnsẹ  lẹyinkunle ni Wasiu ki i mọlẹ, to si fipa ba a sun. Latigba naa ni ẹjọ ọhun ti wa nile-ẹjọ, ṣugbọn lọsẹ yii ni adajọ ṣẹṣẹ too ṣedajọ rẹ.

Agbefọba, Ọgbẹni Babajide Boye, to foju Wasiu bale-ẹjọ sọ ni kootu bayii pe, ‘Oluwa mi, awọn ẹsun ta a fi kan olujẹjọ yii ki i ṣe ẹsun kekere rara, aṣaalẹ ọjọ kan loṣu Kẹta, ọdun 2018, ni olujẹjọ ki ọmọ araale rẹ to jẹ ọmọ ọdun mọkanla lasiko naa mọlẹ lasiko ti ọmọ ọhun fẹẹ lọọ ṣegbọnsẹ, o fipa ba a sun. Ohun ti olujẹjọ ṣe yii ko da a, ijiya wa fẹni to ba ṣe bẹẹ lawujọ wa, o si fẹsẹ ofin gbe ọrọ rẹ lẹsẹ nile-ẹjọ ọhun.

Olupẹjọ tun pe awọn ẹlẹrii mẹrin lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ, gbogbo wọn pata ni wọn sorọ ta ko olujẹjọ yii. Ọgbẹni Wasiu naa pe awọn mẹta kan jade lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, ṣugbọn ṣe lọrọ wọn n ta ko ara wọn.

Adajọ ileejọ ọhun gboṣuba nla fun awọn agbefọba fun iṣẹ gidi ti wọn ṣe lori ẹjọ naa, o si da Wasiu lẹbi pe irọ pọ ju ninu atotonu rẹ.

O ni ko maa lọ sẹwọn gbere gẹgẹ bii ijiya ẹṣẹ rẹ, bakan naa lo ni ki wọn kọrukọ rẹ sinu iwe itan awọn ọdaran niluu Eko.

Leave a Reply