Nibi ti wọn ti n pari ija lawọn agbebọn pa oludasilẹ ṣọọṣi yii si

Adewale Adeoye

Lopin ọsẹ to kọja yii lawọn agbebọn kan ya wọnu ọgba ṣọọṣi kan ti wọn n pe ni ‘Mount Of Solution Redeemed Church’, (MSRC) to wa niluu Ikot-Ekang, nijọba ibilẹ Abak, nipinlẹ Akwa-Ibom. Wọn pa oludasilẹ ṣọọṣi ọhun, Oloogbe Elisha Asuquo, ati pasitọ kan to jẹ alakooso ṣọọṣi  naa, Oloogbe Aniekan Ibanga danu.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meje aabọ aṣaalẹ ọjọ naa ni awọn oniṣẹ ibi ọhun de sinu ipade pataki kan tawọn ọmọ ijọ ọhun n ṣe. Ọkada ni wọn gun wa sibẹ, bi wọn ṣe de ni wọn ti bẹrẹ si i yinbọn soke gbaugbau lati fi da ipaya sọkan awọn ọmọ ijọ ti wọn wa nibi ipade pataki ọhun. Lasiko naa ni wọn yinbọn pa pasitọ yii ati ọkan ninu awọn abẹṣinkawọ oludasilẹ ọhun toun pẹlu jẹ pasitọ.

Ọkan lara awọn araalu ọhun tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe oludasilẹ ṣọọṣi ọhun, Oloogbe Asuquo, ti wọn pa danu jẹ ọmọ agbegbe Adiasim, nijọba ibilẹ Essien Udim, nigba ti pasitọ ti wọn pa, Oloogbe Aniekan Ibanga jẹ ọmọ agbegbe Ikot Obioikpa, nijọba ibilẹ Abak.

O ni, ‘‘Kẹ ẹ si maa wo o, ija nla kan to waye laarin awọn tọkọ-taya meji kan ti wọn jẹ ọmọ ijọ ọhun ni wọn n pari lọwọ ko too di pe awọn oniṣẹ ibi ọhun de sinu ipade pataki ọhun, loju-ẹsẹ ti wọn foju kan oludasilẹ ṣọọṣi ọhun ni wọn ti bẹrẹ si i yinbọn fun un. Lara ọta ibọn ti wọn yin fun un lo ṣeeṣi ba pasitọ kan to wa lẹgbẹẹ rẹ, loju-ẹsẹ loun naa si ku.

O fi kun ọrọ rẹ pe igba akọkọ ree tawọn agbebọn naa maa waa ṣọsẹ niluu awọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, C.S.P Waheed Ayilara, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe awọn ti bẹrẹ si i ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ati pe awọn maa too fọwọ ofin mu awọn ọdaran ọhun.

 

Leave a Reply