Nitori ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara, adajọ sọ akẹkọọ Fasiti KWASU mẹfa sẹwọn n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Adajọ Evelyn Anyadike tile-ẹjọ giga kan n’Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ Ismail Abdulbasit, Ọladipọ Victor, Ibrahim Oluwatosin, Ayantọla Ṣẹgun Samuel, Musbau Waris Atọmọ ati Babalọla Razaq Oluwadamilare, ti gbogbo wọn jẹ akẹkọọ Fasiti KWASU, sẹwọn fẹsun pe wọn n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara tawọn eeyan mọ si ‘Yahoo’.

EFCC lo wọ awọn afurasi mẹfẹẹfa lọ siwaju Onidaajọ Anyadike, fun oniruuru ẹsun pe wọn lu awọn eeyan ni jibiti  lori ẹrọ ayelujara, awọn olujẹjọ mẹfẹẹfa si gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan wọn.

Nigba ti Onidaajọ Anyadike n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ti oun ti ṣe ayẹwo finnifinni lori awọn ẹri ti ajọ EFCC ko siwaju ile-ẹjọ, ti awọn olujẹjọ naa si ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, o ni ki  wọn lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa-mẹfa, ki gbogbo foonu alagbeeka ati kọmputa alaagbeletan ti wọn n lo fun iṣẹ aburu naa di tijọba apapọ, to fi mọ awọn owo ti wọn ba lọwọ wọn.

Ni ti Ibrahim, Babalọla, ati Oluwatosin, adajọ fun wọn lanfaani lati san ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000) gẹgẹ bii owo itanran, ki Ismail, Ọladipọ ati Ayantọla, san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira (100,000), gẹgẹ bii owo itanran.

Leave a Reply