Ile ti Gbenga lọọ ba wọn kun lo ti ji aṣọ ẹgbẹrun lọma ọgọrun-un Naira l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan to n ṣe iṣẹ kunle- kunle (painter) Ọgbẹni Olu Gbenga, ni adajọ ti paṣẹ pe ko maa lọ sẹwọn oṣun mẹrin pẹlu iṣẹ aṣekara nitori ẹsun pe o ji aṣọ alaṣọ gbe.

Ọkunrin yii ni awọn ọlọpaa gbe wa siwaju Onidaajọ Bankọle Oluwasanmi, lọjọ kọkanlelogun, oṣun Kẹta, ọdun 2024, pẹlu ẹsun to rọ mọ ole jija.

Gẹgẹ bii iwe ẹsun ti wọn fi kan ọdaran naa ṣe sọ, ni deede aago mẹrin ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni agbegbe Ibudoko, ni adugbo Oluwatẹdo, Ado-Ekiti, lo ji aṣọ ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira.

Aṣọ naa ni ẹni to ni in, Ọgbẹni Babatunde Bagilaje, sa sori okun ni adugbo naa, ti ọdaran yii si lọọ ka a nibi ti ẹni to ni in sa a si.

Iwa to hu ọhun ni agbefọba ni o lodi sofin iwa ọdaran ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2021. Ninu iwe ẹsun naa ti wọn ka lede Gẹẹsi, ti wọn si tumọ fun ọdaran naa pẹlu ede Yoruba, lo ti jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Ninu ọrọ ọkunrin to ni aṣọ naa lọdọ awọn ọlọpaa, o ṣalaye pe oun sa aṣọ naa sori okun niwaju ile oun nirọlẹ ọjọ naa ni, lojiji loun sadeede wa aṣọ naa, ti oun ko si ri i mọ.

O ni nigba to di ọjọ kọkandinlogun, oṣun Kẹta, ọdun yii, ni oun sadeede ri aṣọ naa lọrun ọdaran ọhun lopopona to lọ lati Ado-Ekiti si Ilawe-Ekiti.

O fi kun un pe bi oun ṣe da a duro ti oun si sọ fun un pe aṣọ oun lo wa lọrun rẹ, niṣe lo ni aṣọ ti oun ṣẹṣẹ ra lọja ni, ṣugbọn lẹyin iṣẹju diẹ ti oun ati ọdaran naa ti wa lori ọrọ yii loun gbe e sori ọkada pẹlu iranlọwọ awọn to wa lagbegbe naa.

Babatunde ni nigba toun de ile loun mu ṣokoto aṣọ naa jade, ti oun si fi han ọdaran naa. Igba yẹn lo ṣẹṣẹ waa jẹwọ pe lọjọ ti oun ba wọn wa kun ile ni adugbo naa ni oun ji aṣọ naa lori okun ti wọn sa a si.

Lati fi idi ọrọ naa mulẹ ṣinṣin, Agbefọba, Ọgbẹni Elijah Adejare, pe ẹlẹrii kan, bakan naa lo ko aṣọ naa silẹ lakooko igbẹjọ gẹgẹ bii ẹsibiiti.

Lẹyin gbogbo atotonu, ọdaran naa ni ki ile-ẹjọ foriji oun.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Oluwasanmi Bankọle, sọ pe ki

ọdaran yii sare lọ si ọgba ẹwọn fun oṣu mẹrin pẹlu iṣẹ aṣekara. Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn da aṣọ ọhun pada fun ẹni to ni in.

Leave a Reply