Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun tẹ awọn afurasi ole meje l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lawọn ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo tun ṣe afihan afurasi ole meje tọwọ wọn tẹ.

Awọn afurasi ọdaran ọhun la gbọ pe ọwọ tẹ kaakiri ilu Akurẹ ati Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lopin ọsẹ ta a lo tan yii.

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ lasiko to n foju awọn ẹlẹgiri ọhun lede ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, Alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ, ni ọkan-o-jọkan iṣẹ ibi lo wa lọwọ awọn tọwọ tẹ naa pẹlu bo ṣe jẹ pe bi wọn ṣe n digunjale ni wọn tun n ji awọn eeyan gbe.

O ni awọn eeyan agbegbe kan niluu Akurẹ, ni wọn pe awọn ni nnkan bii aago kan oru lopin ọsẹ to kọja pe awọn adigunjale kan n ṣọṣẹ lọwọ lọdọ awọn.

O ni awọn ko ti i debẹ tan ti awọn fi pade awọn eeyan kan ninu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry (Big Daddy), ti wọn wa. Njẹ ki awọn da wọn duro lati fọrọ wa wọn lẹnu wo ibi ti wọn ti n bọ láàjìn, ṣe ni gbogbo wọn bẹ jade ninu ọkọ naa, ti wọn si sa lọ.

Adelẹyẹ ni loju-ẹsẹ ni ara ti fu awọn, ti awọn si sare yẹ inu ọkọ naa wo, ọpọlọpọ foonu olowo nla, kọmputa agbeletan atawọn ẹru ẹlẹru mi-in ti wọn gba nibi ti wọn ṣẹṣẹ ti lọọ digun jale lo ni awọn ba ninu mọto naa.

Lẹyin-o-rẹyin lo ni ẹni to ni mọto naa ṣẹṣẹ yọju si awọn lati ṣalaye ọna ti wọn gba digun ja oun ati iyawo rẹ lole loru ọjọ ti wọn wa.

Ọga Amọtẹkun ọhun ni pẹlu gbogbo ipa ti awọn n sa, ko fi bẹẹ si wahala awọn ajinigbe mọ kaakiri ipinlẹ Ondo, nitori gbogbo wakati mẹrinlelogun to wa ninu ọjọ lawọn fi n ṣọ awọn eeyan, paapaa, gbogbo awọn araalu to n gba ọna marosẹ Ọwọ si Ifọn kọja.

O ni ijọba apapọ ati tipinlẹ Ondo ti gbiyanju lati tun awọn ibi to bajẹ ṣe loju ọna marosẹ Ọwọ si Ifọn, leyii to tun ṣokunfa bi iwa ijinigbe ṣe dinku jọjọ lagbegbe naa.

O kilọ fawọn araalu lati sọra fun ri rinrin-ajo loru nitori ewu to rọ mọ ọn pọ pupọ.

Leave a Reply