Ọran nla! Awọn agbebọn ji Imaamu agba gbe ni Kogi

Adewale Adeoye

Bẹẹ ba n ri awọn ọlọpaa atawọn agbofinro gbogbo niluu Iyara, nijọba ibilẹ Ijumu, nipinlẹ Kogi, ti wọn n wọnu igbo ati inu igbẹ kaakiri, Imaamu agba ilu Iyara, Sheik Quasim Musa, tawọn agbebọn kan ji gbe sa lọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni wọn n wa ka.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ naa, lẹyin ti olori ẹsin ọhun de lati mọṣalaṣi to ti lọọ kirun fawọn olujọsin tan lo ba sun siwaju ile rẹ to wa lagbegbe Ilukpa, niluu Iyara, nijọba ibilẹ Ijumu, nipinlẹ Kogi. Nibẹ lo wa tawọn agbebọn kan fi ka a mọ’bi to ti n sun lọwọ, wọn si ji i gbe sa lọ. Niṣe  lawọn araalu ti wọn fẹẹ waa gba a silẹ sa pada nigba tawọn oniṣẹ ibi naa bẹrẹ si i yinbọn soke, ṣe ni kaluku wọn sa asala fun ẹmi wọn lọjọ naa.

Alukoro ẹgbẹ awọn lanlọọdu agbegbe ibi ti wọn ti ji Imaamu ọhun gbe, Ọgbẹni E.K Adebayọ, ṣalaye pe ko sẹni to ronu kan an pe awọn agbebọn le waa ji baba ọhun gbe lasiko yii rara, paapaa ju lọ nigba ti ki i ba eeyan fa wahala kankan laduugbo tẹlẹ. O bu ẹnu atẹ lu bawọn oniṣẹ ibi naa ṣe waa ji Imaamu ọhun gbe sa lọ lasiko awẹ Ramadan yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa S.P Williams Aya, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o lawọn ti da ọpọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ sita, o si ṣeleri pe laipẹ yii lawọn maa gba baba ọhun silẹ lahaamọ to wa.

 

Leave a Reply