Adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun oyinbo Chinese to pa ọrẹbinrin rẹ ni Kano

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Sanusi Ado Ma’ aji, tileejọ giga kan to wa lagbegbe Bompai, nipinlẹ Kano, ni wọn foju oyinbo Chinese kan, Ọgbẹni Geng Quandong, ẹni ọdun mẹtadinlaadota, to pa ọrẹbinrin rẹ, Oloogbe Ummulkusum Sani Buhari, ẹni tawọn eeyan mọ si Ummita, ba lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu  Kẹsan-an, ọdun 2022, ni Geng lọ sile ọrẹbinrin rẹ ọhun nipinlẹ Kano, ọrọ si ṣe bii ọrọ laarin wọn, ki iya oloogbe naa too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Geng ti gun un pa patapata niṣoju iya rẹ. Lo ba sa lọ, kọwọ ma ba a tẹ ẹ, ṣugbọn awọn ọlọpaa pada lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ, ti wọn si sọ ọ sinu ahaamọ wọn latigba naa.

Ninu ọrọ iya oloogbe naa nile-ejọ  lo ti sọ pe, ‘‘Gbara ti oyinbo Chinese ọhun fo fẹnsi ile wa wọle lọ pade mi lẹnu ọna, to si ti mi danu, yakata ni mo ṣubu silẹ. O fibunu wọle lọọ ba oloogbe ninu ile, wọn bẹrẹ si i sọrọ, ẹnu ariyanjiyan ọhun ni wọn wa ti Geng fi yọ ọbẹ si ọmọ mi, o fọbẹ ọhun gun un yannayanna ni gbogbo ara, bi oloogbe ṣe n pariwo to, ko dawọ duro rara, afi igba to ku mọ ọn lọwọ’’.

Geng ṣalaye niwaju adajọ pe, ‘’Oloogbe Ummita kọju mi soorun alẹ patapata pẹlu bo ṣe tan mi jẹ titi, to gba aimọye owo lọwọ mi, to waa lọọ ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin mi-in nigba ti emi si ti n mura silẹ lati waa san gbogbo nnkan idana rẹ fawọn obi rẹ.

‘‘Kẹ ẹ si maa wo o, mo ti nawo-nara, lori oloogbe naa ju pe ko waa ja mi kulẹ lọ, mo ti raṣọ igbeyawo tiye rẹ jẹ miliọnu kan aabọ Naira fun un atawọn aṣọ mi-in ta a maa wọ lọjọ igbeyawo wa. Koda, mo ti ra aṣọ ẹbi ta a maa wọ tiyẹ rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira silẹ. Mo ti ṣẹ owo tuntun ti ma a na loju agbo, ṣugbọn ṣe ni Ummita parọ tan mi, to lọọ ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin mi-in. Pẹlu pe o ti ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin mi-in, ṣe lo n beere owo lọwọ mi nigba gbogbo, igba kan tiẹ wa to wa siluu Kano, nibi ti mo n gbe, mo ti ra ile tiye rẹ jẹ miliọnu mẹrin Naira fun un, ọkọ ayọkẹlẹ miliọnu mẹwaa Naira ni mo ra fun un, bẹẹ ni mo da a lokoowo pẹlu miliọnu mejidinlogun Naira.

‘‘Igba kan tiẹ wa ti mo tun wa si ṣọọbu rẹ, mo raja tiye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ẹẹdegbẹta Naira lọwọ rẹ, mo ra ẹgba ọrun to jẹ goolu fun un, bẹẹ ni mo ti ra ilẹ fun un siluu Abuja, pe ko maa kọle sori rẹ lọ, koda, mo tun fun un lowo pe ko lọ fi gba iwe-ẹri rẹ nileewe to n lọ. Mo n ṣe gbogbo eyi lati sọ fun un pe mo nifẹẹ rẹ gidi, ni ṣugbọn mi o mọ pe o kan n gbe mi mọra ni’’.

Lẹyin tawọn olupẹjọ fawọn ẹri kọọkan han adajọ ile-ejọ ọhun pe ṣe ni Geng mọ-ọn-mọ pa Oloogbe Ummita, adajọ paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

 

Leave a Reply