Ẹwọn gbere ni adajo ju baale ile to fipa b’ọmọ ọdun marun-un sun l’Ekoo si

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Rahman Oṣhodi, tile-ejọ kan to n ri si ẹsun fifipa ba ọmọde sun ati lilo ọmọde nilokulo niluu Eko, ni wọ wọ baale ile kan, Ọgbẹni Ugochukwu Onuoha, to fipa ba ọmọ araale rẹ ti ko ju ọdun marun-un sun ba.

ALAROYE gbọ pe ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni ọdaran ọhun hu iwa palapala naa nibi ti wọn n gbe lopopona Achakpo, niluu Olodi-Apapa, nipinlẹ Eko.

Agbefọba, Ọgbẹni Adedipupo Adewetan, to foju olujẹjọ bale-ejọ l’Ọjọruu, Wsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ niwaju adajọ ile-ejọ ọhun pe, ‘Oluwa mi,  ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2021,  ni olujẹjọ fipa ba ọmọ ọdun marun-un ti i ṣe ọmọ araale rẹ sun lọna aitọ, iya ọmọ ọhun lo lọọ sọ fawọn ọlọpaa agbegbe ibi ti wọn n gbe. Ọdọ awọn ọlọpaa ti olujẹjọ wa lo ti jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọ araale oun ti i ṣe ọmọ ọdun marun-un sun pẹlu ileri pe oun ko ni i ṣe iru nnkan bẹẹ mọ lae.

Wọn gbe ọmọ ọhun lọ sileewosan ijọba to wa lagbegbe nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, esi ayẹwo ti wọn ṣe fọmọ ọhun fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni olujẹjọ yii fipa ba a sun.

Ninu ọrọ olujẹjọ nile-ẹjọ, o gba pe wọn fẹsun iwa palapala kan oun l’ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ṣugbọn o loun ni alaye lati ṣe.

Ninu idajọ rẹ, adajọ gboṣuba fun awọn agbefọba ti wọn foju olujẹjọ bale-ejọ, o ni gbogbo iwadii atawọn ẹri gbogbo to yẹ ki wọn mu wa ni wọn mu wa, paapaa ju lọ, ọrọ  iya ọmọ ti wọn fipa ba sun ko ta ko ara wọn rara.

O ni ki wọn lọọ ju olujẹjọ sẹwọn gbere gẹgẹ bii ijiya ẹṣẹ ohun to ṣe f’ọmọ araale rẹ.

Leave a Reply